Adebutu ni ki Kashamu ma yọ ju, nitori orukọ ẹ ti INEC gbe jade

Spread the love

Fun igba ikẹyin, ajọ INEC gbe orukọ awọn ondije dupo gomina, ile aṣofin atawọn yooku jade l’Ọjọbọ to kọja yii, orukọ Buruji Kashamu ti wọn fọwọ si bii ondije funpo gomina ipinlẹ Ogun lo si tun jade, ti Ladi Adebutu ko si nibẹ. Eyi to mu Ladi kọju si Kashamu pe ko ma yọ ju, nitori igbẹyin ni alayo n ta lọrọ oun yoo pada jẹ ninu ibo yii.

Atẹjade ni Ladi Adebutu fi sita lọjọ keji ti orukọ naa jade, olori ẹka to n polongo fun aṣofin yii, Dayọ Rufai, lo fi atẹjade naa sita lorukọ Ladi.

Ohun ti wọn kọ sibẹ ni pe loootọ ni INEC ko gbe orukọ Ladi Adebutu jade, to jẹ ti Buruji Kashamu ni wọn n ṣe titi dasiko yii. Wọn ni sibẹ, ẹrin ni yoo gbẹyin ọrọ awọn lori ibo yii, nitori igbẹyin lalayo o ta, ko si kinni kan ti yoo ṣenuure fun Kashamu.

Atẹjade naa ṣalaye pe INEC lo n dara to wu wọn, ti wọn n tẹle aṣẹ ẹgbẹ APC to n dari lọwọ. Wọn ni iyẹn lo jẹ ki wọn maa gbe orukọ Kashamu ti ko kopa ninu idibo abẹle jade, ti wọn waa kẹyin si Aṣofin Adebutu to gbegba oroke ninu idibo naa.

Kashamu atawọn eeyan ẹ ko rin irin wọn lọna to tọ gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe ṣalaye,wọn ko si yege. Kaka ki wọn si gba kadara, Kashamu sare gba ile-ẹjọ giga lọ l’Abẹokuta, INEC si bẹrẹ si i ṣe ohun to fẹ pẹlu aṣẹ APC, bi wọn ṣe kọju Adebutu si oorun alẹ niyẹn.

Ṣugbọn Ladi ti ni ki Kashamu ma yọ tori orukọ ẹ to tun  jade yii. O loun mọ pe orukọ ẹ ati tawọn eeyan ẹ to jade ko ja mọ nnkan kan, igba diẹ lo wa fun. Oun Ladi atawọn eeyan oun lawọn yoo rẹrin-in gbẹyin.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.