Adebayọ Shittu, ẹni ojo pa, ti Ṣango o pa …

Spread the love

Ẹni ti ojo pa ti Ṣango ko pa, ko maa dupẹ ni o. Iyẹn ni ọrọ Adebayọ Shittu, minisita Buhari to n mura lati ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ. Ọkunrin naa ti mura gidi, o si ti leri lati ba Gomina Isiaka Ajimọbi fa wahala nla, lati ri i pe ko si bi ipo gomina naa yoo ṣe bọ sọwọ ẹni ti oun Siaka ba fa kalẹ, afi ko bọ sọwọ oun Adebayo Shittu. Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ, nigba ti wọn ri i pe Shittu ko ni iwe NYSC, iyẹn ni pe ko ṣiṣẹ agunbanirọ to yẹ ko ṣe lẹyin to jade ni yunifasiti. Nigba ti awọn igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ APC si jokoo lati yẹ awọn ti yoo dije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ wo lorukọ ẹgbẹ wọn, wọn yọ Shittu si ẹgbẹ kan, wọn ni ko niwee to yẹ ko ni, ko si le ṣe gomina. Ṣugbọn iru ọrọ yii ti ṣẹlẹ si ẹni kan to jẹ niṣe ni wọn yọ ọ nipo to wa, iyẹn Arabinrin Kẹmi Adeọṣun to jẹ oun ni minisita fun eto inawo ilẹ yii tẹlẹ. Oun naa ko ṣiṣẹ sin ilẹ baba rẹ, n lawọn kan ba ba a ṣeto, wọn gbe ayederu iwe NYSC le e lọwọ, igba ti akara si tu sepo lo lọ. Shittu naa ko niwee, akara si ti tu sepo bayii. Ṣugbọn wọn ko yọ oun nipo minisita, bẹẹ ni wọn ko si ti i fi ọlọpaa tabi agbofinro gbe e, nitori bi ọrọ ba de oju rẹ, ọkunrin naa gbọdọ da gbogbo owo oṣu to ti gba lọwọ ijọba lati ọjọ yii wa pada, nitori ko yẹ ko ṣiṣẹ ijọba kan, tabi ko gba owo-oṣu nigba ti ko ṣe agunbanirọ yii. Amọ o da bii pe Shittu ti mu gbogbo iyẹn jẹ, ipo gomina nikan ni ko le du, ilẹkun ipo gomina Ọyọ si ti se mọ ọn ree fun igba pipẹ, afi to ba lọọ fagbalagba ara ṣe NYSC. Nigba ti wọn ko ti gba ipo minisita lọwọ rẹ, ti wọn ko si ba a ṣẹjọ, ẹni ojo pa ti Ṣango o pa niyẹn, ki Adebayọ Shittu yaa maa dupẹ ni.

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.