Adeṣẹgun, igbakeji Amosun tẹlẹ fẹẹ dupo gomina Ogun lọdun to n bọ

Spread the love

Bo ti jẹ pe asiko oṣelu la wa yii, ti awọn oloṣẹlu n fifẹ ọkan wọn lati dije sipo han, Ọmọọba Oluṣẹgun Adeṣegun to jẹ igbakeji Gomina Ibikunle Amosun ni saa akọkọ gomina yii ti fi ipinnu rẹ lati dije dupo gomina ipinlẹ Ogun lọdun to n bọ han.

 

Ọjọ Ẹti to koja yii ni Adeṣẹgun kede ipinnu rẹ fawọn akọroyin n’Iwe Iroyin, niluu Abẹokuta. Ọkunrin naa ṣalaye pe labẹ Ẹgbẹ APC loun ti fẹẹ dije dupo, ohun toun si fẹẹ tori ẹ di gomina ko ṣẹyin pe oun ti ni iriri nigba toun jẹ igbakeji gomina laarin ọdun 2011 si 2015, ọjọ oun si ti pẹ ninu oṣelu gidi.

 

Adeṣẹgun loun mọ ibi ti bata ti n ta awọn eeyan ipinlẹ Ogun lẹsẹ, lati Imẹkọ, de Ijẹbu Waterside, Ipokia, Ọdẹda atawọn mi-in.

O loun yoo ran iṣẹ ọgbin lọwọ, oun yoo ri si eto ẹkọ ni gbogbo ẹka, eto ilera ko ni i gbẹyin lati din iku alaboyun ati tawọn ogo wẹẹre ku, oun yoo ṣeto bawọn ijọba ibilẹ yoo se da duro, iṣẹ yoo si pọ fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lati ṣe.

Imọran lo fi kadii ipinnu rẹ nilẹ, o ni ki gbogbo eeyan lọọ gba kaadi ti wọn yoo fi dibo lọdun to n bọ, ki wọn le fọwọ ara wọn tun aye wọn ṣe nipa yiyan aṣọju rere.

 

 

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.