Adanu nla ni iku Faṣehun jẹ fun gbogbo omo Yoruba- Ajimọbi

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnitọ Abiọla Ajimọbi ti ṣapejuwe iku Oludasilẹ ẹgbẹ OPC, Dokita Fredrick Faṣehun, gẹgẹ bii adanu nla fun gbogbo iran Yoruba ati orileede Naijiria lapapọ.

 

Ninu atẹjade ti Oludamọran fun eto ibanisọrọ rẹ, Ọgbẹni Bọlaji Tunji, fọwọ si, Ajimọbi sọ pe iroyin iku Faṣehun ba oun lojiji pupọ.

 

O ṣapejuwe ọkunrin naa gẹgẹ bii olugbeja iran Yoruba to fi gbogbo aye ẹ ja fun irapada awọn ilu Yoruba ti iji oṣelu ti gbe lọ si iha ibomi-in nilẹ yii. O ni alafo ti ko ṣee di bọrọ ni iku akọni naa da silẹ laarin awọn ọmọ Yoruba.

 

“Dajudaju, yoo ṣoro ka too rẹni bii Faṣehun nilẹ Yoruba ati kaakiri orileede yii, nitori gbogbo igbesi aye ẹ lo lo fun iṣọkan Naijiria.”

O tẹ siwaju pe “gẹgẹ bii oludasilẹ ẹgbẹ OPC, wọn lo ẹgbẹ yii fun jija fun ẹtọ Yoruba lọna ti ohun gbogbo to tọ si awa ẹya Yoruba yoo fi tẹ wa lọwọ ninu eto oṣelu orileede yii.

 

“Wọn jẹ akinkanju eeyan kan ti ki i kó irẹwẹsi ọkan, paapaa lasiko ti ipenija ba doju ẹ tan. Iṣọkan Naijiria ati eto iṣejọba awa-ara-wa jẹ ẹ logun ju ohunkohun lọ. O si wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ NADECO to ja fitafita lati ri i pe ẹtọ Oloogbe M.K.O. Abiọla ti gbogbo Naijiria dibo yan gẹgẹ bii aarẹ orileede yii ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin tẹ ẹ lọwọ”.

 

Ajimọbi ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ OPC ku ara-fẹ-raku ọga wọn to lọ.

 

 

 

(39)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.