Adajọ tu Gedeon tawọn ọlọpaa fẹsun ole kan silẹ

Spread the love

Tiyanu tiyanu lawọn ọlọpaa ilu Ileṣa n wo l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, nile-ẹjọ majisreeti kan to wa niluu naa, nigba ti adajọ kootu ọhun, Adajọ R. A. Ọlayẹmi, beere fun awọn ẹlẹrii ti yoo fidi ẹsun idigunjale ti wọn fi kan Gedeon Joseph mulẹ.
Ọrọ naa bẹrẹ pẹlu bi aṣoju awọn ọlọpaa ni kootu, Ọgbẹni Jimoh, ṣe sọ fun adajọ pe awọn ko ti i ni ẹlẹrii kankan to le tako Gedeon lori ẹsun ole tawọn fi kan an.
Adajọ Ọlayẹmi bu ẹnu atẹ lu iṣọwọ ṣiṣẹ awọn ọlọpaa lori bi wọn ko ṣe ri ẹlẹrii kankan mu wa siwaju ile-ẹjọ naa lati fidi ọrọ wọn mulẹ, bẹẹ naa lo binu ai olori ọgba ẹwọn Ileṣa to kọ lati gbe ọdaran kan, Yusuf Oyebanji, to wa ni ọgba ẹwọn rẹ wa sile-ẹjọ lẹyin ti ile-ẹjọ ti kọwe si i pe ko gbe ọkunrin naa wa.
Aisi ẹlẹrii to le gbe ẹsun ti awọn ọlọpaa fi kan Joseph yii lo mu ki adajọ da ọkunrin naa silẹ pe ko maa lọ layọ ati alaafia. O ni ko sohun to tọ fun oun lati ṣe labẹ ofin ju bẹẹ lọ nigba ti awọn ọlọpaa ko ti le mu ẹlẹrii kankan wa ti yoo ran ile-ẹjọ lọwọ lati gbe idajọ ododo kalẹ fun wọn.
Adajọ Ọlayẹmi waa rọ awọn ọlọpaa pe ki wọn too mu ọdaran kankan wa si ile-ẹjọ, ki wọn ti ṣe iwadii wọn daadaa, ki awọn ẹlẹrii ati ẹri aridaju ti wa nilẹ lati ran ile-ẹjọ lọwọ, ki awọn le ri idajọ ododo gbe kalẹ fun wọn lori ẹjọ ti wọn ba gbe wa si kootu ọhun.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.