Adajọ ti ju Rasaq to ji ẹnjinni bulọọku l’Oṣogbo sẹwọn

Spread the love

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti ni ki ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Amusa Rasaq, lọọ maa ṣere lọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo tun fi waye lori ẹsun ole-jija ti wọn fi kan an.

 

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn fẹsun kan Rasaq pe o lọ sagbegbe Halleluyah, niluu Oṣogbo, nibi to ti lọọ ji awọn eroja ara ẹnjinni ti wọn fi n ṣe bulọọku ikọle ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna aadọfa o le meji Naira (#122,000).

 

Agbefọba to n gbọ ẹjọ naa, ASP Fagboyinbo ṣalaye fun adajọ pe ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ naa ni Rasaq ji silinda ẹnijinni ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ogun Naira, fabiriketọ ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna marundinlogoji Naira, rola ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna mẹẹẹdọgbọn ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Ẹsun ole jija yii, gẹgẹ bi Fagboyinbo ṣe wi, ni ijiya labẹ ori keji abala kẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọṣun ti ọdun 2003.

 

Bo tilẹ jẹ pe olujẹjọ, ẹni ti ko ni agbẹjọro kankan to n ṣoju fun un, sọ pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, sibẹ, o ni ki i ṣe gbogbo nnkan ti agbefọba ka silẹ wọnyi loun ji lọjọ naa.

 

Adajọ O.O. Ọladoke ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii, ti igbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.