Adajọ sun ẹjọ Blessing to pa afẹsọna rẹ nitori oruka siwaju

Spread the love

Onidaajọ Oluwatoyin Taiwo ti ile-ẹjọ giga to wa ni Ikẹja, niluu Eko, ti sun ẹjọ ọmọbinrin kan, Blessing Edet, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ti wọn fẹsun kan pe o pa afẹsọna rẹ nitori ko lo oruka ifẹ (engagment ring), toun fun un. Idi ti wọn fi sun ẹjọ naa siwaju lasiko lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja ni pe agbẹjọrọ olujẹjọ ko si ni kootu. Agbẹnusọ ijọba, Amofin O.A Bajulaiye Bishi, sọ pe agbẹjọro olujẹjọ kọwe ranṣẹ pe ara oun ko ya. Blessing, ẹni to n gbe laduugbo Falana, Ogombo, Lẹkki, niluu Eko, ni wọn fẹsun kan pe o pa ololufẹ rẹ, Ọgbẹni Edet Ebong, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, loru ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2015. Ajọ Akoroyinjọ Naijiria (NAN), jabọ pe Blessing ati afẹsọna rẹ yii ti jọ n gbe papọ, ti Edet si ti fun un loruka to fi ṣadehun pe oun maa fẹ ẹ.

Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2015, ni Edet dari de lati ibi iṣẹ, to si sọ fun afẹsọna rẹ pe ko se ounjẹ foun koun jẹ. Lasiko to n se ounjẹ naa lọwọ ni Edet ṣakiyesi pe Blessing ko lo oruka toun fun un, to si bi i leere. Ọrọ naa lo di wahala ti Blessing fi gun Edet lọbẹ nikun, lẹsẹkẹsẹ lo si jẹ Ọlọrun nipe. Ẹsun ipaniyan ni wọn lo tako abala kan ninu ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n ṣamulo, tọdun 2015.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo gba ọrọ ti agbẹjọro ijọba sọ wọle, o si sun ẹjọ naa si ọjọ keje, oṣu to n bọ.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.