Adajọ so awọn akẹkọọ Adeyẹmi ti wọn fipa ba obinrin lo pọ sẹwọn gbere Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Spread the love

Mẹrin ni awọn akẹkọọ ileewe Olukọni Adeyẹmi, to wa niluu Ondo, ti wọn fẹsun ifipabanilopọ kan, Akinọla Timilẹhin, ẹni ọdun mọkanlelogun, Adebisi Adeyẹmi, ẹni ọdun mejilelogun, Adetuyi Ọlakunle, ẹni ọdun mẹtalelogun ati Tobi Ọlagbaju, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ladajọ ti ran wọn lẹwọn gbere nitori wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

 

Awọn akẹkọọ mẹrẹẹrin naa ni wọn ti n jẹjọ lori ẹsun ifipabanilopọ lati ọjọ kẹta, oṣu keje, ọdun to kọja.

 

Ọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun to kọja, ni wọn kọkọ fara han niwaju ile-ẹjọ majisreeti kan to wa l’Oke-Ẹda, ti wọn si fi ẹsun igbimọ-pọ lati fipa ba ọmọbinrin kan lo pọ kan wọn.

Abilekọ Victoria Bob-Manuel to gbọ ẹjọ wọn nigba naa paṣẹ pe ki wọn ṣi fi wọn pamọ sọgba ẹwọn Olokuta, titi asiko ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.

 

Wọn kọkọ tu wọn silẹ gẹgẹ bii imọran to wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran, ṣugbọn eyi ko tẹ awọn alaṣẹ ileewe Adeyẹmi lọrun, eyi to mu wọn kọwe ẹhonu mi-in, ti wọn si fi dandan le e pe awọn afurasi naa lẹjọ lati jẹ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

 

Lẹyin eyi ni wọn tun pada gbe wọn lọ sile-ẹjọ giga kẹrin to wa niluu Akurẹ.

 

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni Onidaajọ Samuel Bọla to n gbọ ẹjọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ, nibi to ti fidi ẹ mulẹ pe awọn afurasi ọhun jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan wọn.

 

Adajọ ni ki wọn fẹwọn ọdun marun-un jura lori ẹsun igbimọ-pọ lati fipa ba awọn akẹkọọ naa sun, bakan naa lo ni ki wọn lọ ṣẹwọn gbere lori pe wọn jẹbi ẹsun ifipabanlopo.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.