Adajọ ni ki wọn yẹgi fun Sunday to pa ọlọkada niluu Ikire

Spread the love

Lẹyin ti Sunday Palm lo ọdun mẹrin lọgba ẹwọn, adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki wọn yẹgi fun un latari pe o jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.

 

Onidaajọ Adepele Ojo to jẹ adajọ agba nipinlẹ Ọṣun to gbọ ẹjọ naa sọ pe gbogbo ẹri to wa niwaju oun lo fidi rẹ mulẹ pe Sunday jẹbi ẹsun ipaniyan.

 

Ṣe lomi n da poroporo loju Sunday, o si han pe o ti kabaamọ iwa to hu, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, idajọ ti wa lori iwa to hu.

 

Ọjọ kẹjọ, oṣu kejila, ọdun 2014, ni wọn ti kọkọ gbe Sunday wa sile-ẹjọ, ileeṣẹ ọlọpaa si sọ pe o ṣe lodi si abala okoolelọọọdunrun o din mẹrin (316), o si nijiya labẹ abala okoolelọọọdunrun o din ẹyọ kan (319), ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọṣun ti ọdun 2002.

 

Ẹlẹrii mẹta ni awọn agbẹjọro to n wadii ẹsun naa lati ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọṣun, labẹ idari Solicitor General, Dapọ Adeniji, pe lati rojọ tako Sunday, ọpọlọpọ akọsilẹ ni wọn si fi silẹ nile-ẹjọ gẹgẹ bii ẹri, gbogbo rẹ si ni adajọ gba wọle.

 

Adeniji sọ nile-ẹjọ pe ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2006, ni Sunday huwa naa nigba to pa Isiaka Rafiu, ẹni to n ṣiṣẹ ọkada niluu Ikire.

 

O ni lẹyin ọjọ diẹ ni wọn ri oku Rafiu lẹgbẹẹ ọna, o si han gbangba lara rẹ pe lẹyin ijakadi nla ni agbara Sunday bori tiẹ, to si fi jẹpe Ọlọrun.

 

Bakan naa, ninu ọrọ Sunday, o ni loootọ loun jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun, ati pe ṣe loun fi ọbẹ gun Rafiu lọrun lọjọ naa, ti oun si gbe ọkada rẹ sa lọ lẹyin to ku tan.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Nigba ti mo ri Rafiu nibi to ti n ṣiṣẹ ọkada rẹ, mo da a duro pe ko gbe mi lọ si oko kan loju ọna Gbọngan, niluu Ikire. Ki n too kuro nile lọjọ naa ni mo ti mu ọbẹ kan dani, mo di i sinu ọra.

 

“Ba a ṣe de aarin igbo, mo sọ pe ko duro, bo ṣe duro bayii ni mo fa ọbẹ yọ, mo da a dubulẹ pẹlu agbara, mo si fi ọbẹ ge e lọrun, nigba ti mo ri i pe o ti ku tan ni mo gbe ọkada rẹ sa lọ.

 

Onidaajọ Adepele Ojo sọ pe ko si ani-ani kankan, Sunday jẹbi ẹsun ipaniyan, niwọn igba to si jẹ pe iku ni idajọ ẹnikẹni to ba ti paayan, ki wọn lọọ yẹgi fun Sunday titi ti ẹmi yoo fi bọ lara ẹ.

 

 

 

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.