Adajọ ni ki wọn fi ọlọdẹ to n ji waya NEPA ka l’Okitipupa pamọ sọgba ewon.

Spread the love

Ọlọdẹ kan to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ NEPA niluu Okitipupa, Ilen Ayefiwei, ti n kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ Majisreeti to wa niluu ọhun latari ẹsun ole ti wọn fi kan an.

 

Awọn aladuugbo kan la gbọ pe wọn ka ọkunrin ọhun mọbi to ti n ṣiṣẹ buruku ọhun, ti wọn si lọọ fẹjọ rẹ sun ni teṣan ọlọpaa.

 

Ẹsun meji ti wọn fi kan ẹni ọdun mejidinlọgbọn ọhun nigba to n farahan niwaju adajọ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni igbiyanju lati jale pẹlu ole jija.

 

Agbefọba Ayọdeji Ọmọyẹgha sọ pe ni nnkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja lọhun-un ni wọn ka olujẹjọ naa mọ ibi to ti n ji waya to jẹ ti ileeṣẹ NEPA ka lẹyin to ti fi akasọ gun ori opo ina kan to wa loju ọna Ikọya, niluu Okitipupa.

 

Iwa ti olujẹjọ hu yii ni wọn juwe bii eyi to tako abala ofin ẹẹdẹgbẹta o le mẹsan-an (509), ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo, tọdun 2006.

 

Lẹyin ti wọn ti ka ẹsun mejeeji si i leti, to si loun ko jẹbi awọn ẹsun naa ni agbejọro rẹ dide, to si bẹbẹ fun gbigba beeli rẹ niwọn bi ẹsun ti wọn fi kan an ṣe jẹ eyi ti ofin faaye beeli silẹ fun.

 

Adajọ ile-ẹjọ naa, Ọgbẹni D.O. Ogunfuyi, paṣẹ pe ki wọn gba beeli olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ati oniduuro kan niye owo kan naa.

 

O waa paṣẹ pe ki olujẹjọ ọhun ṣi wa lọgba ẹwọn ilu Okitipupa titi ti wọn yoo fi ri beeli rẹ gba.

 

Ọjọ kejila, oṣu yii, ni igbẹjọ tun n tẹsiwaju.

 

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.