Adajọ ni ki Sọji to n jale l’Akurẹ ṣi wa lọgba ẹwọn

Spread the love

Abdul Sọji ti wọn fẹsun kan pe o jẹ ọkan ninu awọn ole to n yọ awọn eeyan ilu Akurẹ lẹnu ni adajọ ile-ẹjọ Majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, ti ni ko ṣi wa lọgba ẹwọn Olokuta, titi di ọjọ ti wọn yoo tun ṣi iwe iranti kan ẹsun ti wọn fi kan an.
Ọkada ti iye rẹ to bi ẹgbẹrun lọna ọgọfa o din mẹrin Naira, ni wọn sọ pe wọn ji gbe lagbegbe Danjuma, niluu Akurẹ, lọsan-an ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.
Ẹsun igbimọ-pọ jale ni wọn fi kan afurasi ọhun, pẹlu bi wọn ṣe loun atawọn kan ji ọkada Bajaj to jẹ ti Ọgbẹni Adeọla Abiọdun, eyi ti wọn lowo rẹ to bii ẹgbẹrun lọna ọgọfa o din mẹrin Naira.
Agbẹnusọ fun ijọba, Amofin David Ebiriku, ninu ẹbẹ to fi siwaju adajọ lo ti jẹ ko di mimọ pe ẹlẹrii mẹrin loun ti ṣeto la ti waa jẹrii tako afurasi ọhun nile-ẹjọ.
Agbẹnusọ ọhun sọ pe oun ti gbaradi lati tẹsiwaju ninu ẹjọ naa, nitori pe gbogbo awọn to yẹ ko jẹrii tako afurasi yii lo wa nitosi.
Abilekọ Adedire to gbẹnusọ fun afurasi ọdaran naa sọ pe oun ko ti i ṣetan fun igbẹjọ, o ni ki adajọ ṣi sun ẹjọ siwaju diẹ na, ko si tun faaye beeli silẹ fun afurasi naa, nitori pe ẹsun ti wọn fi kan an jẹ eyi ti ofin fi aaye beeli silẹ fun.
Ọrọ beeli gbigba yii ni Amofin Ebiriku tako, pẹlu bo ṣe ṣapejuwe afurasi naa gegẹ bii ogboju ole ti ko ṣetan lati ronupiwada.
Ebiriku sọ pe ẹsun meji to jẹ ẹsun ole jija ni afurasi naa ṣi n jẹjọ rẹ lọwọ lawọn ile-ẹjọ kan niluu Akurẹ, ati pe ẹsun mi-in ṣi n bọ lọna ti ile-ẹjọ ko ti i mẹnuba rara.
Adajọ Victoria Bob-Manuel ni ki wọn ṣi fi afurasi ọhun pamọ si ọgba ẹwọn Olokuta, titi asiko ti kootu yoo fi ri imọran gba lori ọrọ rẹ.
Bi adajọ ṣe n pari igbẹjọ akọkọ ni wọn tun pada pe Sọji atawọn meji mi-in, Arowoṣẹgbẹ Tobi ati Amos Daniel, jade pẹlu ẹsun mẹta ti wọn fi kan wọn.
Lẹyin tawọn mẹtẹẹta ti sọ pe awọn ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan awọn ni adajọ gba ki wọn gba beeli awọn ẹmẹwa rẹ mejeeji, ṣugbọn ti adajọ tun paṣẹ pe afi dandan ki wọn ṣi fi Sọji pamọ sọgba ẹwọn, ki awọn araadugbo le sinmi diẹ lọwọ rẹ.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.