Abọ iwadii: Igbimọ alaṣẹ Ekiti ni awọn olori ileewe, ileeṣẹ ṣe aṣemaṣe

Spread the love

Bo tilẹ jẹ pe ko ti i sẹni to mọ ipinnu igbimọ alaṣẹ ijọba Ekiti lẹyin awọn ipade to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ati ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, igbimọ naa ti kede pe awọn ti ṣawari aṣemaṣe awọn olori ileewe ati ileeṣẹ tawọn ṣewadii wọn.

 

Ṣe ni kete ti Gomina Kayọde Fayẹmi de loṣu kẹwaa, ọdun to kọja, lo gbe awọn igbimọ kan dide lati ṣewadii ileewe Ekiti State University, Ado Ekiti(EKSU); College of Education, IkereEkiti; College of Science and Health Technology, Ijero; ileewosan Ekiti State University Teaching Hospital, Ado Ekiti(EKSUTH), ati ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Broadcasting Service of Ekiti State (BSES).

 

Loṣu kejila, ọdun to kọja lawọn igbimọ naa gbe abajade wọn le gomina lọwọ, ẹni to ṣeleri lati ṣiṣẹ lori wọn. Lọsẹ to kọja tigbimọ alaṣẹ jokoo, ti wọn si ṣagbeyẹwo awọn iwadii naa ni wọn fẹnuko pe awọn olori ileewe ati ileeṣẹ naa ti hu awọn iwa kan ti ko bofin mu, ijọba si gbọdọ gbe igbesẹ kia.

 

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lopin ọsẹ to kọja, Yinka Oyebọde to jẹ akọwe iroyin fun gomina ṣalaye pe igbimọ alaṣẹ ti ṣe awọn ipinnu kan tawọn eeyan yoo mọ laipẹ.

 

Ko ṣeni to ti i mọ nnkan tawọn ti wọn fẹsun kan yii ṣe tabi nnkan tijọba fẹẹ ṣe fun wọn, ṣugbọn o daju pe ọrọ ofin lọrọ naa.

 

Awọn to ṣee ṣe kọrọ naa kan ni: Ọjọgbọn Samuel Oyebandele ti EKSU, Ọjọgbọn Mojisọla Oyarekua, ti College of Education, ilu Ikẹrẹ, Lere Ọlayinka ti BSES tẹlẹ, to tun jẹ amugbalẹgbẹẹ Ayọdele Fayoṣe, Dokita Kọlawọle Ogundipẹ ti EKSUTH, ati ọga-agba College of Health Science and Technology ti Ijero Ekiti tẹlẹ, Pasitọ David Ojo.

 

 

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.