Abi ootọ ni Oshiomhole n sọ ni

Spread the love

Abi ootọ ni alaga ẹgbẹ APC jakejado, Ọgbẹni Adams Oshiomhole, n sọ ni. Nigba ti eeyan ba wa nipo agbara bayii, bi agbara ba n gun un, ko si ohun ti ko le sọ. Bo ba yo tan, o le sọ pe oun ni Ọlọrun, afi nigba ti Ọlọrun funra ẹ ba de to ba sọ pe iru ẹni bẹẹ ko jẹ nnkan kan. Adams Oshiomhole ni bi eeyan kan ba ti wọ inu ẹgbẹ APC, ẹṣẹ yoowu to ba ṣẹ, boya o kowo jẹ ni o, boya o paayan ni o, boya o huwa aburu kan ni o, ijọba yoo foriji tọhun, yoo si maa ṣe aye rẹ lọ lai ni i si wahala kankan. Loootọ ni. A ti ri eleyii daadaa, nitori ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn jale tẹlẹ, awọn ti wọn ji owo buruku ko ni gbogbo igba ti wọn wa ninu ẹgbẹ PDP ti wọn ti di ọmọ APC bayii, faaji ni wọn n ba kiri, falala ni wọn n rin, ko sẹnikan to yọ wọn lẹnu. Ṣugbọn ko sẹni to mọ pe iru ọrọ rirun bẹẹ yoo waa ti ẹnu olori ẹgbẹ APC jade, ọrọ ti ko ni oore ti yoo ṣe fun Naijiria ju ifasẹyin lọ. O jọ pe gbogbo ẹni to ba fẹẹ gbe aye rẹ pẹlu alaafia bayii, afi ko wa ninu APC. Lọjọ wo ni a fẹẹ ṣe iru eleyii gba, lọjọ wo ni atunbọtan yoo fi ba gbogbo awọn oniṣẹ-ibi. Ko yẹ ki Oshiomhole sọ bẹẹ, ohun to yẹ ko wi ni pe gbogbo ẹni to ba ṣe daadaa fun Naijiria, gbogbo ẹni to ba n wa ilọsiwaju orilẹ-ede yii, gbogbo wọn ni yoo ni ifọkanbalẹ, ki i ṣe awọn ole to ba sa wọnu ẹgbẹ APC rara. Ọlọrun yoo kuku da a, gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii, beeyan da a ti ko da a re, Ọlọrun yoo tun un da o.

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.