Abi nitori ọrọ sabukeeti yii naa ni

Spread the love

Ọlọrun lo mọ iru yẹyẹ ti awọn eeyan agbaye yoo fi Naijiria ṣe nigba ti wọn ba ri aarẹ wa lori ẹrọ ayelujara to n jo, to n rẹrin-in, ti awọn kan si n ba a yọ pe wọn mu iwe-ẹri oniwe-mẹwaa waa fun un. Tabi kin ni awọn ti wọn mọ pe ayederu ni iwe naa yoo maa sọ, nitori Buhari mọ lọkan ara rẹ, awọn to mu iwe waa fun un mọ, ọpọ awọn ọmọọṣẹ rẹ naa si mọ pe ayederu iwe-ẹri lawọn mu waa fun un. Ṣugbọn Buhari ko lẹbi bii awọn oponu to n ba a jo kiri pe iwe-ẹri tootọ lo mu wa. Ko sẹni ti ko le sọ iwe-ẹri rẹ nu, bi iwe-ẹri ba bọ sọnu, eeyan yoo lọ si ọfiisi WAEC, nibi ti wọn ti ṣe e, wọn yoo si fun un ni eyi ti yoo maa lo kiri. Amọ nigba ti wọn sọrọ sabukeeti fun Buhari lọdun 2015, kaka ko lọ si ọdọ awọn WAEC lati gba iwe-ẹri rẹ, awọn lọọya nla nla mẹtala lo ko jọ pe ki wọn ba oun ro ẹjọ naa ni kootu kẹnikan ma beere esi-idanwo tabi sabukeeti oun lọwọ oun. Bi Buhari ba ni sabukeeti, kin ni yoo fi lọọya to to bẹẹ ṣe? Nigba ti ọrọ di ariwo, ọkunrin yii kan naa lo jade pe ọdọ awọn ṣọja ni iwe-ẹri oun wa, ki awọn ṣọja too jade pe ko si iwe-ẹri rẹ lọwọ awọn. Lẹyin eyi ni awọn ẹgbẹ ajijagbara kan kọwe si ileeṣẹ WAEC ni Ghana, nitori nibẹ ni wọn ti n ṣe eto idanwo yii ni asiko ti Buhari loun jade ileewe, ṣugbọn awọn eeyan ni ko si orukọ to jọ ti Buhari ninu iwe awọn rara. WAEC ti wọn ṣẹṣẹ ko de Naijiria ni 1964 dide burabura, wọn ni awọn mu sabukeeti waa fun un, ṣe Buhari ṣedanwo lọdọ wọn ni! Ki i ṣe owo kikojẹ nikan ni iwa ibajẹ, ṣugbọn eyi ti Buhari n ṣe yii, olori iwa ibajẹ ni. Wọn ti ba ileeṣẹ EFCC jẹ, nibi to ti jẹ kidaa awọn alatako ijọba lawọn yẹn naa n le kiri. Wọn ti ba ileeṣẹ iroyin jẹ, nibi to ti jẹ irọ nla nla lawọn yẹn n pa. Wọn ti ba ileeṣẹ ọlọpaa jẹ, nibi to jẹ ọta Buhari ni ọga ọlọpaa yoo maa le kiri ki iṣẹ ma bọ lọwọ rẹ. Wọn ba ileeṣẹ SSS jẹ, nigba to jẹ wọn o gbe awọn ọga to wa nibẹ ga, afi ki wọn lọọ mu eeyan to jẹ ọmọ ilu wọn tabi ẹya tiwọn wa lati ita. WAEC ti gbogbo awọn ọmọ wa ti n ṣedanwo ni wọn tun n kọ ni irọ buruku yii, wọn yoo pada ba iyẹn naa jẹ ni. Bi ẹ si sọrọ, wọn yoo ni ọrọ buruku lẹ n sọ, tabi ki wọn ni ẹ koriira Buhari ni. Abi nitori ọrọ sabukeeti yii lofin pakaleke yii ṣe jade! Iyẹn o le wọọki; ete ati abuku lo ba de!

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.