Abi ka duro digba ti Ọlọrun yoo yan aṣaaju fun wa funra Rẹ ni

Spread the love

Ọrẹ mi kan fi mi ṣe yẹyẹ, bẹẹ yẹyẹ lo n dun-un-yan. O tẹ atẹjiṣẹ si mi, o ki mi, ki mi; koda, o tun fi adura si i. O waa pari rẹ pe ki n jọọ, nitori Ọlọrun, ohun ti oun fẹ ki n ṣe ni pe ki n gbe apoti ibo, ki emi naa le di aarẹ orilẹ-ede yii. O ni idi ti oun fi n sọ bẹẹ ni pe o pẹ ti oun ti n ra Alaroye, ti oun si ti n ka ọrọ mi nibẹ, pe ko si ijọba kan ti mo sọ pe o ṣe daadaa  ri, afi ki n ṣa maa bu wọn. O ni bi oun ṣe n wo ọrọ yii, ki n di aarẹ Naijiria nikan lo le tẹ mi lọrun o. Niṣe ni mo bẹrẹ si i rẹrin-in nitori ọgbọn nla ti ọrẹ mi yii lo lati fi bu mi, mo si mọ pe awọn mi-in naa wa ti wọn ni ero bayii lọkan: “Ki lo n ṣe baba yii, ko mọ ju eebu lọ, koun naa lọọ gbe apoti, ko waa di aarẹ,” ati awọn ero bẹẹ bẹẹ lọ. Ṣugbọn ki i ṣe bẹẹ rara. Onikaluku lo ni iṣẹ ti yoo ṣe, onikaluku lo ni ọna ti yoo gba ki orilẹ-ede kan too le di nla.

Lara ojuṣe yii ni pe awọn kan ni yoo jẹ oloṣelu, awọn yii yoo maa lọ, wọn yoo maa bọ, iyẹn ni pe bi ẹni kan ba ṣejọba tirẹ loni-in to ba lọ, ẹlomiiran ni yoo pada sibẹ lọla. Awọn kan ni yoo jẹ oṣiṣẹ iijọba, awọn yoo maa ṣiṣẹ fun igba pipẹ titi di akoko ifẹyinti, ijọba oriṣiiriṣii yoo si maa ba wọn lẹnu iṣẹ wọn. Awọn kan yoo jẹ oniroyin tabi abẹnugan laarin ilu, awọn yii ni yoo maa sọ ohun to n lọ lọdọ ijọba fawọn ti ko ba mọ, ti wọn yoo si maa sọ ohun ti araalu n fẹ fawọn to n ṣejọba. Awọn yii ki i ku bọrọ, ati oloṣelu ati oṣiṣẹ ijọba ni yoo ba wọn nibẹ ti wọn yoo si fi wọn sibẹ lọ. Pataki ninu ojuṣe wọn ni lati tọ ijọba sọna, ki wọn si fọna han araalu naa. Iru wọn ko ni i ṣe oṣelu laelae, nitori bi wọn ba ṣoṣelu, ilu yoo bajẹ, nitori iwa ati iṣe wọn ko ba ti oloṣelu mu, ki wọn ronu fun ilu ni iṣẹ tiwọn. Iru ẹ ni mo n ṣe yii, o si tẹ mi lọrun o.

N ko le ṣe iru oṣelu Naijiria yii, nitori n ko le ba wọn ṣe pẹ ti wọn yoo fi pa mi danu nitori ododo sisọ, tabi ki wọn ṣeto ẹwọn fun oluwarẹ nitori agidi, tabi ki eeyan ri ohun ti ko dara ko ma le moju kuro. Awọn ọrọ ti mo n sọ, ọrọ lati tọ awọn eeyan temi sọna ni. Loootọ mo n bu Buhari ati ijọba rẹ, awọn naa mọ pe mo n bu awọn daadaa, ṣugbọn n ko bu wọn nitori wọn jẹ oloṣelu tabi pe mo koriira wọn, nitori pe wọn n ṣe ohun ti ko dara ni. Ki ijọba yii too de ni mo ti sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ nipa rẹ fun yin, mo si sọrọ Buhari fun yin daadaa, inu mi si dun pe ẹyin naa n fi oju ara yin ri i. Ẹ wo gbogbo ariwo ti a n pa, ẹ wo gbogbo eebu ti a n bu, ẹ wo eyi ti Buhari tun ṣe lọsẹ to kọja yii, to yọ olori DSS danu nitori ki i ṣe Hausa, to si lọọ wa Hausa to ti fẹyinti lati gbe sibẹ. Iru ẹni bẹẹ yẹn ko yẹ ni olori Naijiria, aṣiṣe gbaa ni fun wa.

Ko yẹ ni olori Naijiria nitori loju oun, bii ki gbogbo ilẹ yii jẹ ti Hausa Fulani nikan ni, o si fẹẹ fi kinni naa lelẹ debii pe to ba ku tan, gbogbo Fulani ni yoo maa ranti rẹ, ti wọn yoo si maa ṣe adura fun un pe oun lo gba Naijiria fun awọn. Gbogbo igbesẹ ti Buhari n gbe latigba to ti dolori Naijiria, Fulani lo fi n ṣaaju, ko si sohun ti ẹ wi ti yoo tori ẹ yi ọkan rẹ pada. Ohun to ba fẹẹ ṣe ni yoo ṣe, ẹ baa fori sọlẹ. Bi ẹni kan ba jokoo sibi kan, to n ro pe awọn ohun ti Buhari n ṣe nile ijọba yii, fun idagbasoke Naijiria tabi iṣọkan wa ni, tọhun n tan ara rẹ jẹ ni, nigba ti oju iru ẹni bẹẹ yoo ba fi la, nnkan yoo ti bajẹ pata. Eyi ni iru wa ṣe n pariwo. Nigba ti a ti wo saakun ọrọ ti a ri i pe Naijiria ati awọn eeyan ibẹ ti ja sọwọ Buhari bayii, ti ko si jọ pe a le bọ lasiko ibo to n bọ, la ṣe n sọ pe ki Yoruba ṣe ara wọn lọkan, ki wọn laṣaaju ti yoo ja fun wọn.

Bo ba jẹ ti atejiṣẹ ti ẹ n tẹ ranṣẹ si mi ni, tabi ti a ba ni ka dibo nilẹ yii bayii, awọn ọba wa ni yoo jẹ aṣaaju, nitori gbogbo wa la ti jọ gba bayii pe awọn oloṣelu yii ko daa, ifẹ owo ati agbara ojiji ti jaraaba aye wọn. Awọn ti wọn ko jẹ kinni kan laduugbo lanaa, ti wọn ba depo loni-in, wọn yoo bẹrẹ si i ṣe gau gau kiri ilu, ki ẹ si too mọ, wọn yoo maa kọle, ra mọto, wọn yoo si maa fi ọwọ ọla gba awọn eeyan loju, iṣẹ idagbasoke ilu ẹyọ kan bayii ko si ni i tọwọ wọn jade, nitori korofo eeyan lo pọ ninu wọn. Awọn alaye ti ẹ ṣe sinu atẹjiṣẹ yin si mi naa ni mo n sọ yii o, iyẹn lo jọ pe ọpọlọpọ eeyan ṣe ni ki a ba ọba sọrọ, ki a fi awọn ọba ṣe aṣaaju. Pupọ ninu wa lo sọ pe Ọọni Ifẹ lo dara, nitori yatọ si pe ọba naa jẹ baba fun gbogbo Yoruba lati ilẹ wa, ọmọde to leegun lara daadaa ni ẹni to wa nibẹ bayii, yoo si le ṣe ohun ti Yoruba n fẹ fun wọn.

Ọpọlọpọ naa lo sọrọ pe nigba ti Ọọni ba ṣe aṣaaju bayii, ki Alaafin da bii apaṣẹ, tabi alakooso lẹgbẹẹ rẹ, ki ijọba naa si jẹ eyi ti awọn mejeeji yoo jọ maa ṣe, ti awọn ọba bii Awujalẹ, ati awọn ọmọ alade to ku yoo si jẹ igbimọ apaṣẹ, ti wọn yoo jọ maa jiroro lori ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe. Igbagbọ pupọ ninu ẹyin eeyan mi ni pe bo ba jẹ ọba la fi ṣiwaju, nigba ti ọba ko ni i kuro nipo rẹ, afi nigba to ba waja, gbogbo iṣẹ aṣaaju to ba yẹ ko ṣe fun wa ni yoo ṣe. Awọn mi-in tilẹ sọ pe ọba ki i ṣe oṣelu, pe ohun ti yoo jẹ ki wọn wulo fun wa niyẹn, bi a ba si ti ri ọba to ba n ṣe oṣelu, ka ma fi iru ọba bẹẹ si aarin awọn ti yoo ṣe akoso, tabi ti yoo jẹ aṣaaju fun wa. Loootọ awọn kan darukọ awọn eeyan nla bii Ẹgbọn Wọle, Alani, Biṣọọbu Gbonigi, ti awọn kan si sọ pe awọn baba Afẹnifẹre lo daa ju, sibẹ, awọn ti wọn fara mọ awọn ọba yii lo pọ ju.

Bi awọn atẹjiṣẹ to n sọrọ lori awọn ọba wa ti n wọle yii, bẹẹ ni aya mi n lu kii. Bi wọn ba ti darukọ ọba kan, aya mi aa si sọ kulu, awọn ohun ti mo mọ lo si n daamu mi ti mo fi n ronu bẹẹ. Laarin awa Yoruba yii, laarin awọn ọba wa yii, awọn ọba kan wa ti wọn buru ju awọn oloṣelu lọ. Oṣelu tiwọn buru jai, nitori awọn eeyan ko ni i tete mọ pe oloṣelu ni wọn, ka ma ti i waa sọ iru ti Ọba Eko to ti fi ọpọlọpọ igba sọ pe ọba ko le ṣe ko ma ṣe oṣelu, oloṣelu loun, gbogbo eeyan lo si mọ pe awọn APC lo n tẹle. Nigba ti APC n ṣe iforukọsilẹ lọdun kan bayii, Baba wa, Alaafin, funra rẹ bọ si gbangba to forukọ ara rẹ silẹ, boya gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ wọn ni tabi baba ẹgbẹ ni o, mi o mọ. Mo sọrọ naa lọdun naa lọhun-un, o dija, awọn kan mu mi bu ni, pe ko si ohun to kan mi, ẹtọ Alaafin ni lati ṣe oṣelu tabi ko ma ṣe e.

Oun lo delẹ yii o. Bi oloṣelu kan ko ṣe le ṣe aṣaaju fun Yoruba, bẹẹ naa ni ọba to ba n ṣe oṣelu ko le ṣe aṣaaju fun wa. Ọba wo waa ni ki i ṣe oloṣelu, ọba wo ni ko si labẹ awọn oloṣelu lọdọ tiwa nibi, tabi ọba wo ni awọn oloṣelu ki i paṣẹ fun, ọba wo ni wọn ki i da riboribo sibi to ba wu wọn, njẹ ọba kan wa laarin awa ti awọn oloṣelu ki i kọnturoolu, ṣe ọba kan wa ti Bọla yoo pe ti ko ni i sare lọ, tabi ti Bọla yoo lọ si aafin rẹ ti ko ni i ṣe ohun to ba fẹ fun un. Ọba wo ni.

Gbogbo ọrọ ti mo n sọ yii, ẹ ma wo mi bii alaṣeju tabi bii alainitẹlọrun o, mo n sọ ọ ka le jọ gbe e wo sọtun-un sosi ni. Bo ba jẹ laye ọjọsi ni, bo ba jẹ laye ti nnkan ko ti i bajẹ ni, ko si ẹni ti ipo aṣaaju Yoruba yoo tọ si ju ọba lo. Ṣebi bo ṣe wa nilẹ Britain, iyẹn ilu oyinbo, nibi ti Ọba obinrin (Queen), ti n ṣe olori wọn niyẹn. Ki lo ṣẹlẹ si ọba ilu oyinbo, ki lo de ti oun fi niyi, to si laṣẹ lẹnu, ti awọn ọba tiwa si wa bi wọn ti ṣe wa yii? N o ṣalaye diẹ lori iyẹn lọsẹ to n bọ, a oo si gbe ọrọ awọn ọba yii yẹwo, ka le mọ ohun ti a oo ṣe.

Ẹnikan ti sọ pe Ọlọrun nikan ni yoo yan aṣaaju fun Yoruba, nitori Ọlọrun nikan lo n fi aṣaaju jẹ, ki i ṣe eeyan. Ṣugbọn a o ṣaa tilẹ fi ẹni kan digẹrẹwu ki ẹni ti Ọlọrun ba yan naa too de. Awọn kan ni emi gan-an lawọn fẹ, mo rẹrin-in titi, nitori mo mọ pe abẹnugan laarin ilu ki i ṣe aṣaaju, o le ba nnkan jẹ ju ko tun un ṣe lọ. Ọlọrun yoo gbe aṣaaju dide fun Yoruba, ṣugbọn ẹ jẹ ka gbiyanju lọkan ati laaye tiwa naa, ki Ọlọrun si gbe ẹni ti ọkan wa ba mu fun wa.

 

(25)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.