Abetele Riba ni Eze ati Solomon fẹẹ gba lọwọ awọn eeyan ti wọn fi balẹ si kootu

Spread the love

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja ni ajọ EFCC, wọ Dandy Eze  ati Solomon Johnson, lọ siwaju Adajọ Mojisọla Dada, ti kootu  to n gbọ ẹsun to ba jẹ mọ awọn iwa ọdaran to ni i ṣe pẹlu owo to wa ni Ikẹja, niluu Eko. Ẹsun mẹrin, eyi to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ huwa ọdaran ati gbigba riba ti iye rẹ to aadọta miliọnu Naira, ni wọn fi kan wọn.

Atẹjade ti ajọ naa fi sita ṣalaye pe niṣe ni wọn beere owo yii lọwọ ileeṣẹ WAHUM Nigeria, wọn ni awọn le ba wọn ṣe e ti Ajọ EFCC yoo fi fa iwe ẹsun ti awọn kan kọ tako ileeṣẹ naa niwaju rẹ ya.

Awọn afurasi naa ti gba miliọnu kan Naira lara owo naa, asunwọn Solomon Jonson ni wọn si san an si.

Gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan wọn nile-ẹjọ ṣe ṣalaye, wọn ni Eze, ẹni to jẹ aarẹ ẹgbẹ Path of Peace Initiatives pẹlu Solomon Johnson, gbimọ-pọ lọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun to kọja, niluu Eko, wọn si lọọ beere aadọta miliọnu Naira gẹgẹ bii riba lati fa iwe ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ Wahum ya niwaju ajọ naa.

Awọn olujẹjọ ni awọn ko jẹbi ẹsun yii. Agbẹnusọ ajọ EFCC, George Chia-Yakua, rọ ile-ẹjọ lati fun awọn lọjọ ti awọn yoo le ko awọn ẹlẹrii wa si kootu. Agbẹjọro awọn olujẹjọ, Terry Adeniji, ṣalaye fun ile-ẹjọ pe oun ṣẹṣẹ gba iwe ipẹjọ ti wọn fi wọ awọn onibaara oun wa si kootu ni, o si rọ adajọ lati fun oun lọjọ perete, ki oun baa le ka iwe naa daadaa. O rọ adajọ lati fi awọn afurasi naa pamọ si ọdọ ajọ EFCC.

Onidaajọ Dada paṣẹ pe ki awọn olujẹjọ naa ṣi wa lahaamọ ọgba ẹwọn, o si sun ẹjọ wọn si ọjọ kẹrinla, oṣu to n bọ.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.