Aarin Ladọja atawọn adari ẹgbẹ PDP ti daru

Spread the love

Nnkan ko lọ deede mọ laarin Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Sẹnetọ Rashidi Ladọja, atawọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, o si ṣee ṣe ki oun atawọn alatilẹyin ẹ ya kuro ninu ẹgbẹ naa ni igbakugba si asiko yii.

Lati bii oṣu kan nilẹ yii niroyin yii ti n ja ran-in ran-in nilẹ nigba tawọn to sun mọ Ladọja sọ pe awọn pẹlu ọga awọn ti n ṣiṣẹ labẹnu lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD), ṣugbọn ti ọkunrin agba oloṣelu ọhun funra ẹ dakẹ jẹẹjẹ, ko sọ ohun to n ṣẹlẹ gan-an fẹnikan.

 

Ṣugbọn ni bayii, gomina atijọ naa ti fidi iroyin ọhun mulẹ f’ALAROYE, o ni bi wọn ṣe n ṣe ninu ẹgbẹ PDP ko ba oun lara mu rara.

Ladọja, ẹni to ba akọroyin wa sọrọ nipasẹ Alhaji Lanre Basheer Latinwo ti i ṣe akọwe iroyin ẹ sọ pe oun ti n mura lati kuro ninu ẹgbẹ PDP nitori aṣemaṣe ti ẹgbẹ ọhun ti ṣe sẹyin lo mu ki oun pinya pẹlu wọn. Eyi si lawọn adari ẹgbẹ naa lapapọ ṣeleri lati ṣatunṣe si ko too di pe oun gba lati pada sinu ẹgbẹ naa, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe awọn iwa buruku ọhun lawọn eeyan naa tun ti rawọ le bayii.

 

Gẹgẹ bo se sọ, ”Lẹyin igba ta a ti dibo abẹle tan lati yan awọn adari ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ yii (Ọyọ), awọn alaṣẹ ẹgbẹ lati Abuja tun wa n gbe igbesẹ lati paarọ diẹ ninu awọn ta a ti dibo yan, ki wọn si fi awọn mi-mi-in rọpo wọn. Bẹẹ Yoruba bọ, wọn ni ba a ba fagbo feegun, a a ju okun ẹ silẹ ni. O yẹ ki wọn le fi awọn oloye ẹgbẹ ni ipinlẹ silẹ lati dari ẹgbẹ ni ipinlẹ wọn.”

(51)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.