Aarẹ Buhari loun ko ni i dẹkun gbigbogun ti iwa ibajẹ lorileede yii

Spread the love

Aarẹ orileede yii, Alhaji Muhamadu Buhari ti ṣeleri pe ti awọn araalu ba le fun oun lanfaani lati ṣe aarẹ lẹẹkeji, oun ko ni i dẹkun gbigbogun ti iwa ibajẹ ti iṣejọba oun ti dawọle.

 

Lasiko ipolongo ibo to ṣe sipinlẹ Ọṣun, nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti gba a lalejo ni papa iṣere ilu Oṣogbo lo ti ni o digba ti iwa ibajẹ ba kuro nilẹ yii patapata ki ilọsiwaju tawọn araalu n reti too le waye.

 

Buhari, ẹni to ni oun ko ni i sinmi titi ti gbogbo awọn oloṣelu jẹgudujẹra yoo fi foju winna ofin fidi rẹ mulẹ pe igbẹkẹle tawọn araalu ni ninu oun gẹgẹ bii aarẹ ti ko gba igbakugba laaye lo jẹ ki wọn maa tu jade logun-lọgbọn ni gbogbo ipinlẹ tipolongo ibo ti n waye.

 

Ni ti eto aabo, Buhari ni ọpọlọpọ awọn ilu ti ikọ Boko Haramu ti gbajọba wọn koo to di pe iṣejọba oun bẹrẹ lọdun mẹrin sẹyin lawọn ọmọ ologun ti gba pada bayii, ti awọn olugbe ilu naa si ti n fẹdọ le ori orooro.

 

Ninu ọrọ Asiwaju Bọla Hammed Tinubu lo ti ni ijọba Buhari ti ṣetan lati tẹsiwaju ninu igbedide iṣẹ agbẹ lorileede yii, o ni aimọye awọn ọmọ Yoruba nijọba APC ti gba ṣiṣẹ, bẹẹ ni Aarẹ Buhari ti sọ ọjọ kejila, oṣu kẹfa, di ilumọn-ọn-ka kaakiri.

 

Bakan naa, alaga ẹgbẹ APC lorileede yii, Adams Oshiomole, sọ pe awọn ọmọ orileede yii ni wọn yoo fi ọwọ ara wọn juwe ibi ti okun yoo wọ lara akeregbe, ko ni si aaye fun magomago lasiko idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun yii rara; eeyan kan, ibo kan ni yoo si jẹ.

 

Ṣaaju ni Buhari ti ṣepade papọ pẹlu awọn lọbalọba ipinlẹ Ọṣun labẹ alaga wọn, Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, ninu ile ijọba to wa l’Oke-fia, niluu Oṣogbo.

 

Nibẹ ni Buhari ti rọ awọn ori-ade bii aadọrun-un ti wọn pesẹ sibẹ lati ba awọn araalu wọn sọrọ lori idi to fi yẹ kijọba ẹgbẹ oṣelu APC tẹ siwaju lorileede yii, awọn ọba naa si ṣeleri atilẹyin wọn fun un.

 

Lara awọn ti wọn tun wa nibi eto ipolongo naa ni Oloye Adebisi Akande, Rotimi Amaechi, Rauf Arẹgbẹṣọla, Gomina Gboyega Oyetọla, Ọtunba Iyiọla Omiṣore, Ọmọọba Gboyega Famọdun, Oluṣọla Oke, Fẹmi Adeṣina, Festus Keyamọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.