Aafaa Abdulraham ma n ṣere ni bebe ẹwọn, ọmọ ile-keu rẹ fipa ba lo pọ l’Ẹdẹ

Spread the love

Florence Babaṣọla

Wọn n pe ọrọ ọhun lowe, o da bii ẹni pe o fẹẹ maa laro ninu bayii pẹlu bi ọmọ ọdun mẹrindinlogun to sọ pe aafaa kan fipa ba oun lo pọ ṣe sọ ni kootu pe ti awọn mọlẹbi oun ba le gba lati fọwọ ile tọ ọrọ naa, ṣe loun yoo pa ara oun si wọn lọrun.

Loṣu to kọja ni wọn wọ aafaa kan niluu Ẹdẹ, Habeebullah Abdulraham lọ sile-ẹjọ Majisreeti ilu naa lori ẹsun mẹta ọtọọtọ. Agbefọba sọ pe aafaa yii gbe ọmọdebinrin naa pamọ, o fipa ba a lajọṣepọ, o si ṣe e baṣubaṣu.

O ṣalaye nigba naa pe ọkan lara awọn ọmọ keu aafaa Abdulraham ni ọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun, wọn ni ọkunrin naa tan an lọ sibi eto kan niluu Ilaro, nigba akọkọ to fipa ba a laṣepọ.

Nigba ti wọn beere bi ọrọ ṣe jẹ lọwọ aafaa, ṣe lo sọ funle-ẹjọ pe iyawo oun ni ọmọdebinrin to wa ni ipele kẹta akọkọ nile-ẹkọ girama (JSS 3) ati pe oun ti tọrọ rẹ lọwọ awọn mọlẹbi ẹ. Ṣugbọn iya ọmọ yii ati ẹgbọn rẹ ọkunrin to pẹjọ sọ pe irọ pata ni aafaa naa n pa.

Nigba ti wọn kọkọ wa sile-ẹjọ, Onidaajọ Olowolagba gba beeli Aafaa Abdulraham pẹlu oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele owo-oṣu kejila, to si ni ilẹ sagbegbe ile-ẹjọ, lẹyin naa ni adajọ sun igbẹjọ si ọjọ keji, oṣu kẹjọ, ọdun yii, nigba ti agbẹjọro olujẹjọ sọ pe o ṣe e ṣe ki awọn yanju ọrọ naa nitubi-inubi.

Nigba ti wọn dele-ẹjọ lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, awọn agbẹjọro mejeeji sọ pe awọn ko ri ọrọ naa yanju latigba ti awọn ti kuro nile-ẹjọ, idi si niyi ti adajọ fi sọ pe ki igbẹjọ kuku bẹrẹ ni pẹrẹu lori ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ ti a wa yii.

Ṣugbọn bi wọn ṣe bọ sita ile-ẹjọ ni ọmọdebinrin naa sọ fun awọn oniroyin pe ṣe lawọn agbẹjọro mejeeji n sọ tara wọn o, ati pe ohun ti oun n fẹ ni toun ni idajọ ododo, o ni ṣe ni ki ofin ṣe iṣẹ ọwọ rẹ lori ọrọ naa. O ni nnkan kekere kọ loju oun ti ri lori ọrọ naa latigba to ti ṣẹlẹ, ati pe ẹnikẹni to ba n gbero pe ki wọn tọwọ ile bọ ọrọ naa kan n reti iku oun ni, nitori pe oun le para oun ti wọn ko ba faaye gba aafaa lati foju winna ofin.

Bakan naa ni ẹgbọn ọmọ naa to kọkọ pe ẹjọ gan-an, Muyideen Oloyede, sọ pe latigba ti awọn ti wa sile-ẹjọ gbẹyin, ẹnikẹni ko yọju si awọn fun ọrọ kankan, o ni koda, bi wọn wa, ohun kan ṣoṣo ti awọn yoo sọ pe awọn fẹ ni ki idajọ otitọ fẹsẹ mulẹ lori ọrọ naa.

O ni loootọ loun gbọ pe aafaa atawọn kan lọọ ṣepade pẹlu awọn agbaagba inu mọlẹbi awọn, ṣugbọn wọn ko pe oun toun pe ẹjọ sibẹ, bẹẹ naa ni wọn ko pe ọmọ ti ọrọ kan sibẹ, wọn ko si jẹ ki ẹnikan ti wọn pe lara awọn ẹgbọn ọmọ ọhun sọrọ kankan nibẹ.

Oloyede ni, ‘gbogbo ọna ti wọn yoo fi ṣe ọrọ naa wuruwuru lawọn kan n wa, ṣugbọn ohun ti awa fẹ ni idajọ ododo, aafaa gbọdọ kọkọ gba pe oun jẹbi awọn ẹsun ti a fi kan an ko too di pe a maa mọ igbesẹ to ku’.

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.