Aafa Salaudeen to fipa ba ọmọ keu rẹ lo pọ ti wa lahaamọ

Spread the love

Nitori bo ṣe fipa ba ọmọ ọdun marun-un to n kọ ni kewu lo pọ, ileeṣẹ ọlọpaa ti wọ Aafa Abdulsalam Salaudeen, ẹni ọdun mẹtalelogoji, lọ si kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, ti ọkunrin naa si loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an. Salaudeen, ẹni to n gbe lojule kẹrindinlogun, adugbo Awoyẹmi, Igando, Ikọtun, niluu Eko, ni wọn fi ẹsun ijabaale ẹni lọna aitọ kan.

Inspẹkitọ Benson Emuerhi, ẹni to n rojọ tako o niwaju Adajọ Olufunkẹ Sule-Amzat, sọ pe ọjọ kejilelogun, oṣu to kọja, ni Salaudeen huwa naa ninu mọṣalaṣi Ọlọrungbẹbẹ, to wa ni Iyan Ile-Ọba, Igando, niluu Eko. Emuerhi ni gbajumọ aafaa ni afurasi ọdaran naa laduugbo yii. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ẹnikan to n gbe lagbegbe ọhun lo mu iroyin iṣẹlẹ naa lọ si ileeṣẹ ọlọpaa.

Ṣaaju lawọn ọlọpaa ti ṣalaye pe ẹnikan to ri Salaudeen nibi to ti n ka itan ọmọdebinrin to yẹ ko maa kọ ni kewu naa soke, to si n ko ibasun fun un lo ya fidio rẹ, to si fi ranṣẹ si Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Imohimi Edgal. Kọmisanna naa lo paṣẹ pe ki wọn gbe afaa yii, ko si pẹ rara tọwọ  fi tẹ ẹ nitosi mọṣalaṣi kan to wa ni Igando.

Lasiko ti awọn ọlọpaa gbe e de ẹka to n ri si ọrọ lakọ-labo nileeṣẹ ọlọpaa ni wọn fi fidio naa han, lẹsẹkẹsẹ si lo jẹwọ pe loootọ loun huwa naa.

Adajọ Olufunkẹ Sule-Amzat ti sun ẹjọ naa si ọjọ keje, oṣu keji, ọdun yii, o si paṣẹ pe  ki wọn ṣi maa mu olujẹjọ naa lọ si ọgba ẹwọn Kirikiri, titi asiko ti amọran yoo fi jade lọdọ ẹka to  n gba adajọ nimọran lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.