A maa mojuto eto ijoba ibile Awọn araalu la maa fun lanfaani lati yan awọn to ba maa dari eka yii – Lanlẹhin

Spread the love

Kinni kan lo mu eto oṣelu ipinlẹ Ọyọ dun nipa idibo to ku ku dẹdẹ yii. Iyẹn ni bo ṣe jẹ pe ki i ṣe awọn to n dupo oṣelu lorukọ awọn ẹgbẹ ta a ti n foju wo gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu nla nikan lawọn eeyan n foju si lara gẹgẹ bii ẹni to ṣee ṣe ko wọle idibo yii, tọtẹ yii ti kuro lọrọ APC ati PDP nikan. To ba waa jẹ tawọn to n dupo gomina ipinlẹ Ọyọ ni, ọkan ninu awọn oludije dupo to lẹnu nibẹ ni Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹhin. Ọkan ninu awọn ẹgbẹ tuntun ta a si n royin yii, ẹgbẹ oṣelu Ọlọwọgbọwọ, iyẹn Action Democratic Congress (ADC), lo fa a kalẹ lati dupo gomina lorukọ wọn. Odu ọkunrin naa ko ṣajeji soloko awọn eeyan lagbo oṣelu. Ninu ifọrọwerọ rẹ yii lẹ o ti mọ ohun to fa ipinya laarin ọkunrin to fẹẹ ṣe gomina yii pẹlu agba oṣelu to ti ṣe gomina ipinlẹ naa nigba kan ri, Sẹnetọ Rashidi Ladọja, atawọn nnkan mi-in.

 

 

ALAROYE: Ẹ ti ṣe ẹgbẹ oṣelu ACN, Akọọdu (Accord Party), PDP, ẹ ko tun pẹ nibẹ tẹ ẹ fi gba inu ADC tẹ ẹ wa yii lọ, kin nidi tẹ ẹ fi n tinu ẹgbẹ kan bọ si omi-in?

Lanlẹhin:  Ninu ẹgbẹ PDP, a ti ri i pe wọn ti pinnu lori ẹni ti wọn maa fun ni tikẹẹti lati dupo gomina. Wọn gba pe ko si anfaani fun ẹnikẹni lati du awọn ipo kan nitori pe wọn ti ni awọn ti wọn fẹ ko di ipo yẹn mu lọkan ara wọn. Ṣugbọn emi fẹ ki wọn fun gbogbo wa lanfaani kan naa lati jọ dupo to ba wu wa nitori emi fẹẹ sin awọn araalu ni temi.

 

ALAROYE: Ṣe iru ẹ ko ṣẹlẹ ninu ADC naa ni, ṣebi ohun to n bi awọn kan ninu ni pe wọn ko jẹ ki idibo abẹle waye lati fa awọn oludije kalẹ?

Lanlẹhin: Iru ẹ ṣẹlẹ naa, ṣugbọn iyatọ to wa nibẹ ni pe ninu ẹgbẹ PDP, wọn ti foju si ẹni kan ṣoṣo lara, wọn si ti gba pe ẹni yẹn naa lo gbọdọ dupo lorukọ ẹgbẹ. Nigba ta a de inu ADC, a ri i pe o ṣe e ṣe ki  wọn fun gbogbo wa pata lanfaani kan naa lati dupo. Mo ranti pe lẹyin ti wọn ṣayẹwo fun wa tan, awọn adari ẹgbẹ sọ fun gbogbo awa oludije pe, “ẹ ẹ ṣe lọọ ṣepade funra yin kẹ ẹ yan ẹni kan ninu yin”. Awa funra wa la yari ta a sọ pe awọn aṣaaju wa la fẹ ki wọn yan fun wa. Ninu awa mẹtala ta a fẹẹ ṣe gomina ninu ẹgbẹ yii, awọn mẹrin lọ sinu ẹgbẹ mi-in, awa mẹsan-an yooku si gba lati jọ ṣiṣẹ pọ.

 

 

ALAROYE: Ẹkun agbegbe Isẹyin, Kajọla, Isẹyin, Itẹsiwaju ati Iwajọwa ni wọn jọ maa n pin ipo to ba pa gbogbo wọn pọ laarin ara wọn, ṣugbọn ọmọ Isẹyin nikan lẹgbẹ yin fun ni gbogbo ipo to kan gbogbo ẹkun yẹn; ṣẹ ẹ ro pe awọn ijọba ibilẹ mẹta yooku lagbegbe naa ko ni i fi ibo wọn yi ẹgbẹ yin lagbo da sina?

Lanlẹhin: A ti ṣalaye fun awọn ara Isẹyin pe ki wọn ma binu. Ṣe ẹ mọ pe ẹgbẹ to ba pọ to jẹ̣ pe ẹgbẹ oṣelu to wa ninu ẹ pọ, ko si bi eeyan ṣe le ṣe nnkan ti ko ni i ku sibi kan. A ti jẹ ki wọn mọ pe a ṣi maa ṣatunṣe nigba ta a ba de ori aleefa. Ọpọlọpọ ipo lo wa nilẹ ta a ṣi maa yan awọn eeyan si, awọn ipo kọmiṣanna wa nilẹ, oludamọran pọ nibẹ, ipo sinu igbimọ ileeṣẹ ijọba atawọn ipo mi-in loriṣiiriṣii. A si ti ba wọn sọ ọ, awọn naa ti gba bẹẹ.

 

ALAROYE: Lẹyin tẹ ẹ ti jawe olubori gẹgẹ bii ẹni ti yoo dupo gomina lorukọ ẹgbẹ ADC lawọn eekan oṣelu bii Agba-oye Ladọja ati diẹ ninu awọn tẹ jọ dupo gomina nigba yẹn ti fi ẹgbẹ yin silẹ, njẹ ẹ ko ro pe eyi le ṣakoba fun ẹgbẹ yin ninu eto idibo to n bo?

Lanlẹhin: Ko le ṣakoba fun un. Ninu awa mẹtala ta a jọ dupo, awọn mẹrin lọ, awa mẹsan-an to ku si jọ fẹnu ko pe ka maa tẹsiwaju. Koda, awọn to lọ paapaa ko pa wa lara nitori o faaye silẹ fun awọn kan. Iba dun mọ mi ninu ti wọn o ba lọ o, nitori ka rin ka pọ, yiyẹ ni i yẹ ni. Ṣugbọn a ko le di wọn lọwọ nigba ti wọn sọ pe awọn n lọ. Mo le fọwọ sọya pe ẹgbẹ Ọlọwọgbọwọ lo fẹsẹ rinlẹ ju.

 

ALAROYE: Bawo lẹ ṣe le gbe ijọba yii lori oṣunwọn?

Lanlẹhin:  Ijọba to wa nibẹ yii, ijọba awọn kọgila ni, ijọba ba mi kin ẹyin mi ki emi naa ba ọ kin ẹyin rẹ, ijọba mọlẹbi. Ẹnu mi gba a nitori ebi, airiṣẹ, ailera, iṣẹ atoṣi ti pọ ju niluu lasiko ijọba yii. Ijọba to wa nibẹ yii ko fi tọmọniyan ṣe.  Gbogbo ohun ti wọn mọ ni ka fẹẹ kọ ile kan jan-an-ran, ki wọn gbe kọntiraati fawọn eeyan lati ilu okeere, nigba ti iya n jẹ awọn araalu, ti ebi n pa wọn, ti wọn ò riṣẹ ṣe. Awọn nnkan keekeeke ti ko yẹ ki ijọba maa fi ni awọn eeyan lara ni wọn fi n ni wọn lara. Owo to n wa lati Abuja too gbọ bukaata, ṣugbọn ijọba yii ko mọ bi wọn ṣe n nawo lọna to tọ lo n jẹ ki ijọba wọn le koko mọ awọn araalu. Ẹ ṣe biriiji to jẹ pe ida mẹta ti awọn kan ṣe nibomin-in lẹyin n ṣe ni ilọpo mẹta ẹ. Ko yẹ ko ri bẹẹ. Ijọba ò sanwo fun oṣiṣẹ atawọn oṣiṣẹ-fẹyinti, awọn mi-in wa ninu wọn ti wọn ko ti i gbowo fun ọdun kan aabọ. Ẹ wo LAUTECH, o ti n lọ si bii ọdun meji bayii ti wọn ti n yanṣẹ lodi. Ṣe awọn le lọmọ nibẹ ki wọn maa woran. Nitori pe ọmọ tiwọn ko si nibẹ ni wọn ṣe n woran ki eto ẹkọ bajẹ. Ko sibi tẹ ẹ de tawọn eeyan ko ni i maa ṣaroye, koda, bẹ ẹ de inu oko. Ti Ọlọrun ba gba fun wa, ta a ba dori aleefa, ijọba tiwa-n-tiwa la maa ṣe.

 

ALAROYE: A fẹ kẹ ẹ gbe ara yin paapaa leri oṣunwọn laarin ẹyin tẹ ẹ jọ n dupo gomina.

Lanlẹhin:  Lakọọkọ, mo ni iriri ijọba. Ti wọn ba n sọ nipa ijọba, ẹka mẹta lo ni, ẹka alaṣẹ, aṣofin, ati ẹka idajọ. Ko si ibi ti mi o ti i gba kọja nibẹ. Iṣẹ̣ lọọya ni mo kọ. Mo ti ṣe aṣoju-ṣofin ati aṣofin agba. Mo ti ṣe kọmiṣanna, oludamọran, mo ti ṣe olori igbimọ ileeṣẹ ijọba apapọ. Mo ti ṣe gbogbo ẹ. Eeyan le maa ṣeleri pe oun yoo sọ oke dilẹ, ṣugbọn ẹ beere lọwọ ẹ pe ṣe o ti inu ẹ wa. Gbogbo eyi ti emi n ṣe, mo n ṣe e nitori ifẹ araalu ni, ki i ṣe lati ko ọrọ jọ, lati kọle si London, kọle s’Amẹrika. Awọn eeyan la fẹẹ sin. Ohun tawọn eeyan nilo lati gbe igbe-aye rere ko pọ, ki wọn jẹun, ki wọn wa lalaafia, ki wọn si kawe. Ewo ni kawọn perete kan maa pin nnkan ijọba. Nigba ti eeyan n ṣejọba, to sọ pe oun maa kọ ileetura nla sẹgbẹẹ Premier Hotel, oteeli meji a waa wa lẹgbẹẹ ara wọn, awọn nnkan ti ko nitumọ. Ṣe ijọba gidi niyẹn? Gbogbo ohun to wa nilẹ too pin. Gbogbo bo ṣe n ka mi lara, to n dun mi to, mo gba pe gbogbo bi mo ṣe sọ ọ ni mo maa ṣe.

 

 

ALAROYE: Kin ni kawọn ara ipinlẹ Ọyọ maa reti bẹ ẹ ba di gomina?

Lanlẹhin:  Ijọba mi maa pese iṣẹ. A maa ṣeto abule idako to maa ni awọn ohun eelo amayedẹrun lati jẹ ki awọn ọdọ maa dako. A si maa wa awọn ileeṣẹ to maa ra awọn ere oko yẹn fun lilo ti wọn aa maa rowo na. Ẹlẹẹkeji, eto ẹkọ. Ọrọ a n gba ẹgbẹrun kọọkan Naira lọwọ awọn akẹkọọ gegẹ bi ijọba to wa lode yii ṣe n ṣe ko ni i si ninu ijọba tiwa. A maa tun awọn ileewe to ti bajẹ ṣe, a si maa kọ tuntun. Awọn araalu naa la maa gbe awọn iṣẹ atunṣe yẹn fun, awọn to n ṣiṣẹ ọwọ bii kafinta, birikila, abbl naa la maa gbe iṣẹ ijọba fun. Awọn ọna wa ti ko daa, a maa tun wọn ṣe. Awọn ọna inu ilu, gbogbo koto yẹn la maa di. Awọn nnkan wọnyi ko na ijọba lowo nla. Eyi to maa n dun mi ju ni ki ọmọ jade nileewe ko ma riṣẹ laarin ọdun meji. Awọn eeyan nifẹẹ si ere idaraya, ṣugbọn ijọba yii ko naani ẹ. Ẹ wo ipo ti awọn papa iṣere ta a ni ni ipinlẹ yii wa, wọn ti sọ Lekan Salami to wa ni Adamasingba  di gbọnga ayẹyẹ, papa iṣere Olubadan ati tilu Ogbomọṣọ ko ṣe e ri soju. Ijọba mi maa da idije bọọlu silẹ laarin awọn ileewe to jẹ tijọba ni ipinlẹ yii. Eyi yoo le tete mu idagbasoke ba ere idaraya. Gbogbo ohun to ba si gba la maa fun un lati ri i pe ẹgbẹ agbabọọlu ipinlẹ Ọyọ (Shooting Stars Sports Club, 3SC) gba agbega si ipele liigi agba ọjẹ nilẹ yii.

 

ALAROYE: Nigba ti Sẹnetọ Ladọja fẹẹ kuro ninu ẹgbẹ ADC, a gbọ pe wọn bẹ yin lati jẹ ki awọn jọ maa lọ sinu ẹgbẹ oṣelu ZLP, ṣugbọn ẹ ko gba. Igbagbọ awọn kan ni pe niṣe lẹ dalẹ wọn.

Lanlẹhin:  Gbogbo wa pinnu pe ki gbogbo wa jọ ṣe ADC. Ẹgbẹ ADC, igun marun-un lo wa nibẹ, CNM, Accord, ADC tẹlẹ, Unity Forum latinu ẹgbẹ ***APC… Bo tilẹ jẹ pe ko kọkọ dan mọran bii gilaasi nigba ta a kọkọ jọ para pọ di ọkan, gbogbo wa la gba pe ajọṣepọ wa maa daa nigbẹyin. Iyẹn la ṣe pinnu lati fi suuru yanju awọn ede-aiyede to wa laarin wa nigba yẹn. A a si ti ri i yanju. Ṣugbọn ta a ba ni ka tun kuro nibẹ, ki lo fi da wa loju pe ohun to le wa kuro ninu ADC ko tun ni i ṣẹlẹ nibi ta a ba lọ. Mo si fọrọ lọ awọn eeyan, wọn lawọn o lọ, ẹni kan ki i si i jẹ awade. Ẹ ṣewadii awọn to tẹle Oloye Ladọja, wọn kere pupọ, koda, titi to fi mọ awọn to sun mọ wọn gan-an ni. Mi o fẹẹ sọrọ pupọ nipa Oloye Ladọja, nitori wọn daa si mi, ẹgbọn mi daadaa ni wọn.

 

ALAROYE: Ati ẹ gbọ pe ẹyin gan-an bẹ wọn lati ma fi ẹgbẹ ADC silẹ ati pe iyẹn gan-an lo da wọn duro ti wọn ko fi tete lọ sinu ZLP. Ṣe loootọ ni?

Lanlẹhin:  A jọ ṣepade, wọn si ṣeleri pe awọn maa ṣiṣẹ fun mi, afi bi wọn tun ṣe sọ pe awọn n lọ sinu ẹgbẹ ZLP. Mi o fẹẹ sọrọ pupọ lori ẹ.

 

ALAROYE:  Kin ni ipinnu yin lori ọrọ hijaabi to n da awuyewuye silẹ ni ipinlẹ Ọyọ lọwọ lọwọ yii?

Lanlẹhin:  Ma a pe gbogbo awọn ti ọrọ kan ni, a ma a jọ jokoo, a maa jọ sọ ọ. Atawọn ẹlẹsin musulumi ati kirisitẹni atawọn ẹlẹsin ibilẹ. Ṣẹ ẹ mọ pe nilẹ Yoruba, ko si ẹbi ti ko ni ẹlẹsin meji tabi mẹta ninu.

 

ALAROYE:  Ẹka tabi iṣẹ wo lẹ ro pe o nilo amujuto kiakia tẹ ẹ ni lati tete mojuto bẹ ẹ ba dori aleefa?

Lanlẹhin:  Ijọba ibilẹ ni. Eto iṣejọba ibilẹ la maa mojuto. Wọn ti sọ ọ di apa kan ijọba ipinlẹ. Wọn kan n ṣe e bii ẹka ijọba ibilẹ ni. Ṣugbọn oun gan-an lo yẹ ko ṣe pataki ju nitori oun lo sun mọ awọn araalu ju. Awọn araalu mọ ẹni to le ṣe e ati ẹni ti ko le ṣe e. Ibẹ niṣẹ si pọ si ju. Awọn araalu la maa fun lanfaani lati yan awọn to ba maa dari ijọba ibilẹ bẹrẹ latori alaga de awọn supa ati kansilọ. A o si ni i toju bọ owo wọn, nitori iṣẹ wọn pọ, ileewosan, awọn oṣiṣẹ, atunṣe ọna ati bẹẹ bẹẹ lọ, ki i ṣe pe ka maa fi wọn di gẹrẹu lasan.

 

(23)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.