A maa ṣe atilẹyin to gbopọn fun Atiku- Saraki

Spread the love

Olori ile igbimọ aṣofin agba, Dokita Bukọla Saraki, ti ki Alaaji Abubakar ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lati ṣoju ẹgbẹ naa ninu ibo aarẹ ọdun to n bọ ku oriire. Bẹẹ lo ṣeleri pe awọn yoo ṣe atilẹyin fun un. Saraki  ni oun mọ pe ki i ṣe ohun ti oun nikan le da ṣe, o ni awọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ pẹlu rẹ, ki awọn si fun un ni atilẹyin to ba yẹ nigbakuugba to ba pe awọn lati ṣe bẹẹ.

O fi kun un pe bi ko tilẹ pe awọn paapaa, tidunnu tidunnu lawọn yoo fi ṣiṣẹ fun un lati ri i pe awọn yege ninu eto idibo to n bọ ọhun.

Bẹẹ lo gboriyin fun awọn agbaagba ẹgbẹ naa, paapaa julọ, awọn ti wọn ṣeto idibo abẹle yii, o ni iṣẹ takuntakun ni wọn ṣe.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.