A ko ni i ṣatilẹyin fun oludije ti ko ba wa lati Ariwa Kwara

Spread the love

Awọn eeyan ẹkun Ariwa Kwara ti ni awọn ko ni i ṣatilẹyin fun oludije ti ko ba ti wa lati ẹkun idibo naa. Wọn ni asiko ti to fun ẹkun naa lati di ipo gomina ipinlẹ Kwara mu.

Ẹgbẹ kan ti ki i ṣe ti oṣelu, CKNG (Coalition of Kwara North Group) lo fi ẹdun ọkan wọn han si bi wọn ti ṣe gba ẹkun Ariwa Kwara sẹgbẹẹ kan fun ọdun pipẹ, to si jẹ pe ẹkun Aarin Gbungbun ati Guusu nikan lo n ṣejọba.

Lasiko ti wọn n ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ẹgbẹ naa sọ pe ẹkun mẹta lo wa nipinlẹ naa, aparo kan ko si ga ju ọkan lọ, afi eyi to ba gun ori ebe.

Wọn ni ohun ti awọn ẹkun meji yii lẹtọọ si naa ni awọn to wa lati Ariwa ni ẹtọ si.

Ẹgbẹ ọhun sọ pe bi awọn ti ọrọ oṣelu Kwara kan ko ba dahun si ẹbẹ awọn ara ẹkun yii, awọn ko ni i kopa ninu idibo gomina lọdun to n bọ.

Bakan naa lawọn ko ni i gba oludije yoowu ti ko ba wa lati ẹkun idibo naa laaye lati waa polongo ibo ni agbegbe awọn

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.