Aṣọna fipa ba ọmọ ọdun marun-un lo pọ ninu ṣọọṣi, o lẹmii eṣu lo ya oun lo

Spread the love

Alaye to pọ ni ọkunrin aṣọna kan, Saviour Udoh, ṣe fun awọn ọlọpaa bo ṣe jẹ pe inu ṣọọṣi lo tun ti ni ẹmi eṣu ba le oun, to fi di pe o n ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun marun-un kan sun lasiko iṣo-oru.

Saviour, ẹni to jẹ aṣọna ninu ijọ Ridiimu (Redemption Pavillion), to wa laduugbo Oṣhifila, Anifowoshe, Ikẹja, ni wọn lo fipa ba ọmọdebinrin to jẹ ọmọ ọkan ninu awọn ọmọ ijọ naa sun lasiko ti wọn wa niṣọ-oru.

Ajọ ti n ja fẹtọọ awọn ọmọde ti wọn firoyin yii sita ṣalaye pe igbagbọ iya ọmọ naa ni pe ko si ohun ti yoo ṣe ọmọ oun nile Oluwa, idi niyẹn to si ṣe fi i silẹ ko sun sinu ṣọọṣi. Nigba to maa pada wọnu ṣọọṣi, niṣe lo ri Udoh lori ọmọ rẹ, ṣugbọn ko tete ka igbesẹ naa si nnkan kan. Lasiko ti wọn n pada lọ sile ni ọmọ naa bẹrẹ si i yun oju ara, ti atọ si n da jade latibẹ.

Nnkan ti iya ọmọ yii ri niyi to fi beere ohun to ṣẹlẹ, ọmọ naa si ṣalaye pe Udoh lo fa a. Lẹsẹkẹsẹ lobinrin yii mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa MAN Centre, awọn ni wọn si wọ aṣọna naa lọ si ẹka to n ri si ọrọ lakọ-labo nileeṣẹ ọlọpaa fun iwadii.

Udoh jẹwọ fawọn ọlọpaa, o ni loootọ loun huwa naa, ṣugbọn ẹmi eṣu lo ya oun lo ninu ṣọọṣi. Awọn ọlọpaa ko fi akoko ṣofo ti wọn fi taari rẹ lọ si kootu Majisreeti to wa l’Ọgba, niwaju Adajọ B.O Ọṣunsanmi, ẹni to kọ lati faaye beeli silẹ fun un.

Ọjọ kẹfa, oṣu to n bọ, lo sun igbẹjọ aṣọna naa si.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.