Aṣọgba lu akẹkọọ pa ni Ipọnri, o lo ri oun fin Kayọde Ọmọtọṣọ

Spread the love

Fẹmi Aderohunmu, aṣọgba ileewe girama Jubril Martins Memorial Grammar School, to wa ni Ipọnri, niluu Eko, ni awọn ọlọpaa ti mu bayii fun ẹsun ipaniyan,wọn lo lu akẹkọọ ileewe naa, Adagun Rafiu, ẹni ọdun mẹrindinlogun pa. Atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Bala Elkana, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ṣalaye pe Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Elkana sọ pe ni nnkan bii aago mẹta ku ogun iṣẹju ni awọn alaṣẹ ileewe Jubril Martins mu ẹsun lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Ipọnri pe Fẹmi ṣadeede da akẹkọọ awọn kan to wa ni ipele kẹta agba (SS3), Adagun Rafiu, ẹni ọdun mẹrindinlogun, lọna laduugbo Oke-Olu, to wa ni Ipọnri, nibi to si ti n ba a ja ni ọmọkunrin naa ti ṣadeede ṣubu lulẹ. Awọn eeyan to wa nibẹ lo sare gbe Rafiu lọ si ọsibitu Smith Medical, ṣugbọn nibẹ lọmọkunrin naa pada dakẹ si.

Alukoro ni iwadii fi han pe lasiko ti Rafiu n dari lọ sile lẹyin to pari idanwo Wayẹẹki tan ni afurasi na lọọ da a lọna, ẹsun to si fi kan an ni pe ọmọkunrin naa ri oun fin.

A gbọ pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Yaba ti ṣabẹwo si ibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti gbe oku oloogbe naa pamọ si mọṣuari fun ayẹwo. Fẹmi yoo si foju ba kootu fun ẹsun ipaniyan.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.