Aṣiwaju Tinubu pẹlu awọn agbero Eko

Spread the love

Ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii niluu Eko, nibi ti ẹgbẹ APC ti n ṣe ipolongo wọn ko ya ọpọ awọn eeyan lẹnu. Awọn ti wọn mọ ajọṣe buruku to wa laarin Aṣiwaju Bọla Tinubu ati awọn ọga awọn agbero l’Ekoo ti mọ tẹlẹ pe iru awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ ree, o le pẹ, o le ya ni. Nigba ti ẹ ba n darukọ awọn kan bii Talo Skibo, MC Oluọmọ, Koko Zaria, Hamburger, Esi Oluwo, Kunle Poly, Owoseni, Nayam, Mamok, ọga awọn tọọgi ni gbogbo awọn yii, awọn tọọgi ti wọn n lo orukọ ẹgbẹ awọn onimọto lati fi ṣe iṣẹ wọn. Wọn ki i ṣe tọọgi bẹẹ yẹn o, tọọgi miliọnia ni wọn, owo buruku wa lọwọ wọn. Amọ ko si ibi ti wọn ti ri awọn owo yii ju ọdọ awọn oloṣelu lọ, ko si si eyi to lorukọ gidi ninu wọn ti ko sun mọ Aṣiwaju Tinubu. Wọn maa n fi awọn tọọgi yii halẹ mọ awọn ẹgbẹ alatako ni, wọn si maa n lo wọn lati ji ibo gbe tabi lati le awọn eeyan danu nibi ti ogun ba ti le. Ni 2015 ni wọn pa Esi Oluwo nitori pe o lọ sinu ẹgbẹ PDP, ẹgbẹ naa si sọ gbogbo ibo ti wọn di l’Oṣodi nu lasiko naa. Awọn eeyan Aṣiwaju pe ọkunrin yii, wọn kowo fun un, lo ba pada sinu APC, ọjọ to pada naa ni wọn gun un pa nibi ipolongo APC. Ni 2017 ni wọn pa Hamburger, l’Oṣodi yii kan naa, ti awọn ọmọ ẹyin rẹ si n sọ pe MC Oluọmọ lọwọ ninu iku rẹ. Yatọ si owo buruku ti awọn agbero yii n fi tipatipa gba lọwọ awọn onimọto, awọn oloṣelu yii tun maa n ko owo fun wọn ti wọn ba ti fẹẹ ṣe kampeeni, wọn yoo ni ki wọn ri i pe awọn bọisi wọn wa nibẹ daadaa. Ohun to n ki awọn eeyan yii laya ree, ohun to si jẹ ki wọn di eṣu ọdara saarin ilu fun gbogbo ẹni to ba n gbe ilu Eko niyẹn. Oṣelu ti a n ṣe ti a n lo awọn tọọgi lati fi dẹruba awọn araalu, iru oṣelu wo niyẹn. Ijọba ti a n ṣe ti owo to wa lọwọ awọn tọọgi ju owo to wa lọwọ awọn ti wọn n ṣiṣẹ loju mejeeji lọ, ijọba were ni, ki i ṣe ijọba awọn ọlọgbọn. Ilu ti a ba wa ti ọlọpaa n ṣọ tọọgi kaakiri, ti tọọgi n ṣe ohun to ba wu u, tawọn to n fi oju mejeeji ṣe iṣẹ lẹyin ọpọlọpọ iwe ti wọn ka ko ri aabo kankan lori wọn, ohun gbogbo ti dorikodo niyẹn, yoo si ṣoro ki ilọsiwaju kan too ba wa. Ọpọ awọn agbero ti wọn n da Eko ru yii, orukọ APC ni wọn fi n ṣe bẹẹ, orukọ Aṣiwaju ni wọn n lo, nitori ọmọ Aṣiwaju ni wọn n pe ara wọn kaakiri. Afi ki Aṣiwaju funra rẹ yẹra fawọn eeyan yii, tabi ko jade si gbangba ko sọ pe oun ko ran tọọgi kan niṣẹ, ko jade ko ni oun ko mọ MC Oluọmọ, atawọn ọmọ ẹyin rẹ, ko si sọ pe agbero tabi tọọgi tọwọ ba ti tẹ, kawọn agbofinro ṣe e bo ba ti yẹ. Bi ko ba ṣe bẹẹ, Eko yii yoo maa bajẹ si i, nigba to ba si ya, ẹnikan yoo pe oun naa lati waa ṣe iṣiro gbogbo ohun to ṣe. O le da bii pe bi aye yoo ṣe maa ri titi lọ ree, ti agbara yoo wa lọwọ wọn titi ti wọn yoo fi ku, ṣugbọn itan oriṣiiriṣii ti fihan pe aye yii ko ri bẹẹ, awọn ti wọn jaye lanaa da, ki i ṣe gbogbo wọn naa lo ti ku, agbara aye lo fi wọn silẹ lọ. Ori oniru, ori alata, ori ọmọde, ori agba ko ṣadura fawọn ti wọn n da Eko laamu, fawọn ti wọn n ko hilahilo ba awọn

eeyan ilu, gbogbo ẹni to ba lọwọ si iwa bẹẹ ko jawọ o.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.