Aṣiwaju ti di wolii agba, o riran bajẹ!

Spread the love

Loootọ oloṣelu ni gbogbo eeyan mọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu si, ṣugbọn o jọ pe oṣelu rẹ ti tun fi kinni kan tayọ ti awọn oloṣelu to ku nilẹ yii gbogbo, baba naa ti bẹrẹ si i riran. Iran lati inu ẹmi, tabi lati ori-oke nla ni. Nibi ipade APC ti wọn ṣe ni Abuja, Aṣiwaju Tinubu sọ fun gbogbo awọn ti wọn wa si ipade naa pe oun riran, oun si mọ ni amọdaju, pe eto ti ẹgbẹ PDP ti ṣe kalẹ ni lati fi ọgọta (60) ọdun maa ji owo awọn ọmọ Naijiria ko. O ni nigba ti oun waa riran bẹẹ, ti ẹmi si ba oun sọrọ loun ba ni, ”haa, ṣe a oo maa waa wo awọn araabi yii niran ki wọn ji gbogbo owo Naijiria ko ni”, iyẹn lawọn ṣe da ẹgbẹ APC silẹ, bo tilẹ jẹ pe inu bi awọn PDP. O ni iran ti oun ri nigba naa ti n ṣiṣẹ, nitori awọn PDP ko ri owo ilu ji ko mọ. Ohun to ṣẹlẹ ni pe o da bii pe ọrọ PDP yii ti di nnkan mi-in si Aṣiwaju Tinubu lara, ko jọ pe baba naa maa n ri nnkan mi-in mọ afi PDP, ohun kan ṣoṣo to ni lati fi polongo oṣelu ati ibo niyẹn, afi PDP ṣaa! Ẹgbẹ wọn ti ṣejọba fun ọdun mẹta bayii, wọn n lọ si ọdun kẹrin, loootọ lawọn ole PDP ti lọ, awọn ole tuntun ti APC lo wa bayii, ṣugbọn Tinubu ko riran ri awọn yẹn, wọn di i loju ẹmi! Gbogbo ohun meremere ti APC ni awọn yoo ṣe laarin ọdun meji si mẹta, ko si ọkankan to ṣee ṣe nibẹ, wọn ni ko sowo lapo ijọba, ṣe awọn Tinubu ko ri i ninu iran ọjọsi pe ko si owo ni. Awọn ti wọn n jale lọwọlọwọ ni ba a ti n sọrọ yii, ṣe eleyii tun di igba ti Tinubu ba lọ si ori-oke ko too ri wọn ni. Iṣoro to wa fawọn oloṣelu ilẹ yii ni pe opurọ ni wọn, ẹlẹtan ni wọn, wọn ko si ni i sọ ododo fun araalu nigba kan. Awọn ti wọn pọ ju ninu awọn aṣaaju APC yii naa loni-in, ṣebi awọn PDP ọjọsi naa ni, abi ewo waa ni ọrọ ti Aṣiwaju n sọ yii. Awọn ti wọn fẹẹ ji owo ko fun ọgọta ọdun ninu PDP nijọsi, awọn naa ni wọn wa ninu APC loni-in, wọn ṣi n ji owo wọn ko lọ lai fi ti ọta pe, awọn ọga APC nikan ni wọn ni awọn ko ri i. Ọlọrun yoo ṣaanu yin, ṣugbọn ki ẹyin naa ṣe aanu ara yin o, nitori lọjọ kan, araalu yoo mọ gbogbo ohun to n lọ, ati awọn ohun ti ẹ n se tile fi n jo!

(128)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.