Aṣiwaju, iru ọrọ wo niyẹn

Spread the love

Aṣiwaju Bọla Tinubu sọrọ kan lọsẹ to kọja nigba ti rogbodiyan to ṣẹlẹ nile-igbimọ aṣofin n lọ lọwọ. Ọkunrin oloṣelu ilẹ Yoruba naa ni ohun to fa wahala nile-igbimọ aṣofin nigba naa ni pe awọn Saraki pẹlu awọn aṣofin ẹlẹgbẹ rẹ fẹẹ pade lati yọ olori ijọba Naijiria, Muhammadu Buhari, ohun ti awọn SSS ṣe le wọn niyi, ati pe iru ete bẹẹ ko ni i ṣee ṣe laelae. O fẹrẹ jẹ gbogbo eeyan lọrọ naa ya lẹnu, nitori gbogbo wọn pata lo mọ pe irọ ni Tinubu n pa. Awọn eeyan ilu mọ pe Buhari, Oshiomhole atawọn aṣaaju APC ni wọn fẹẹ yọ olori ile-igbimọ aṣofin, wọn mọ pe gbogbo ọna ni wọn n wa lati ṣe bẹẹ. Ọrọ oṣelu ni, ko si sohun to buru nibẹ, bi wọn ba ri i ṣe, daadaa naa ni, ko ṣa ti jẹ pẹlu ọna to bofin mu. Ṣugbọn lati jade lati maa waa pe araalu ni oponu ati ọdẹ, lati maa sọ ohun ti ko ṣẹlẹ, lati maa fi irọ buruku bo ododo ọrọ loju ki i ṣe ohun to dara rara, bo ba si dara, ko tọ si iru awọn eeyan bii Aṣaaju Tinubu. Awọn Yoruba fẹran Tinubu ni gbogbo ọna, wọn si tẹle e lati igba to pẹ titi di asiko yii, ṣugbọn lati waa sọ wọn di mumu, ko si maa purọ fun wọn nitori ati ri ojuure lọdọ Buhari ati awọn eeyan rẹ, ko si ohun ti yoo ti idi eyi jade ju ẹtẹ ati abuku lọ. Njẹ o dara ki iru Tinubu maa sọrọ ki awọn eeyan maa poṣe, ṣugbọn ohun ti yoo ṣẹlẹ niyẹn bi ko ba ṣọra ẹ, to ba jẹ ko lero meji fun wọn bayii mọ ju ko maa fi ojoojumọ purọ fun wọn lọ. Bi eeyan ba tẹle eeyan kan, to si ri i pe aṣiṣe loun ṣe lati tẹle iru ẹni bẹẹ, iyẹn ki i ṣe ẹṣẹ, nitori ko si ẹni to gbọn tan. Ṣugbọn olori ẹṣẹ ti ko ni idariji lọdọ Ọlọrun paapaa ni ki eeyan kan, aṣaaju kan, ko ri i pe ibi ti oun dorikọ yii ko si ọna nibẹ, igbo ni, ko si ni ki awọn eeyan oun maa lọ sibẹ, nigba ti oun si tadi mẹyin to n wa ọna ti yoo gba sa lọ. Eleyii ko daa, ẹ sọ fun Aṣiwaju Tinubu ko ma ṣe bẹẹ mọ o, nitori oun naa gbọdọ mọ pe Yoruba ki i foriji ọdalẹ, wọn yoo maa sọrọ rẹ laidaa titi aye ni.

(129)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.