Aṣiwaju, ẹ jawọ nbẹ, ere egele ni

Spread the love

Iroyin to n jade yii ko daa o. Wọn ni gbogbo ọna bayii ni Aṣiwaju Bọla Hammed Tinubu ati awọn aṣofin Eko n wa lati ri i pe wọn yọ Gomina Akinwunmi Ambọde nipo ko too di ọjọ ti yoo gbejọba Eko silẹ. Ohun to le fa idi eyi ko ye ẹnikan, ṣugbọn bi aye ko ba ri wọn ki i sọ, ọrọ naa ti kari ilu, ẹnu awọn to si ti n jade, ẹnu awọn to sun mọ Aṣiwaju funra rẹ ni. Oriṣiiriṣii ọrọ ni wọn n sọ pe o fa eleyii, wọn ni Ambọde ri Aṣiwaju fin ni lati sọ pe oun yoo kọntẹẹsi nigba ti Aṣiwaju ti sọ fun un pe ko jawọ nibẹ; wọn ni wọn ko le gbẹrii ọkunrin naa jẹ bo ṣe wa yẹn, nitori bi wọn ba fẹẹ nawo Eko lati fi ṣeto kampeeni fun ibo gomina to n bọ naa, o le ni oun ko lowo ti oun yoo gbe silẹ, bi wọn ba fẹẹ nawo ibo lati du ipo aarẹ fun Ọgagun Buhari naa, o le ni oun ko lowo, ki eleyii ma si ṣe ṣẹlẹ tabi ko ba ẹnikẹni lojiji ni wọn ṣe kuku ni ki awọn yọ ọ ko maa lọ. Gbogbo ẹjọ ti wọn ro kalẹ ati gbogbo ọrọ ti wọn sọ yii, ko si eyi to jẹ nitori araalu ninu ẹ. Boya o ri Aṣiwaju Tinubu fin, laarin oun ati ẹ niyẹn, ṣe oun lo fa a kalẹ tẹlẹ, ko si si ijiya to tun tobi ju ko ri i pe o kuro nipo naa gẹgẹ bo ti ṣe lati ri i pe wọn ko tun fa a kalẹ ninu ẹgbẹ wọn. Ṣugbọn lati da iṣakoso ipinlẹ Eko ru nitori rẹ, lati yọ ọ kuro nipo ko too di ọjọ ti awọn araalu dibo yan an, lati gbe sombi kan sibẹ ti yoo le nawo araalu lai mọṣiro, iyẹn yoo le diẹ, ẹtẹ ati abuku ti yoo si ko ba Tinubu funra rẹ, boya ni Aṣiwaju yoo bọ ninu rẹ titi ti wọn yoo fi gba Eko naa kuro lọwọ gbogbo wọn. Eebu alọ ni ti ahun, tabọ ni ti ana rẹ: bi awọn araalu ati awọn oloṣelu ba bu Ambọde pe o ri awọn agba fin, ko jẹ ki wọn jẹ owo Eko bi wọn ṣe fẹ, bi awọn ti wọn fi i wọlẹ yii ko ba waa pada lẹyin rẹ, ti wọn ba n le e pe afi kawọn yọ ọ ni ipo gomina, awọn ni aye yoo pada bu, ki i ṣe eebu nikan ni wọn yoo si maa bu wọn, wọn yoo tun gbe wọn ṣepe leralera, bi epe ara ilu ba si ja, ori ẹni to ba ja le ki i gbadun tile-tile ni o. Ki Aṣiwaju yaa gbe jẹẹ, ki oun naa mọ pe aye ko lọ bii ọpa ibọn, ko mọ pe igba la a ni, ẹni kan ki i ni ile aye, bi ko ba tete ku, gbogbo ohun to ṣe yii ni yoo pada ri abọ rẹ. Bo ba jẹ daadaa lo ṣe, yoo ri i ti awọn eeyan yoo maa gbe ọwọ ati apọnle fun un titi ti yoo fi ku, to ba si jẹ ẹtan ati ibajẹ lo ṣe, nigba ti aṣiri ba tu, yoo ri i ti awọn eeyan yoo maa da ṣiọ oun, ti wọn yoo si sọ ọ di ẹni ipati titi ti yoo fi ku. Ki Tinubu ṣe e diẹdiẹ, nitori ohun ti i tan leegun ọdun, bẹẹ ọwọ epo laye n ba ni la o, bo ba di ọwọ ẹjẹ, kaluku wọn ni yoo sa lọ.

(106)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.