Aṣeyọri wa nipinlẹ Eko ko ṣẹyin Ọlorun

Spread the love

Nitori awọn aṣeyọri rere ti ijọba rẹ ti gbe ṣe nipinlẹ Eko lati ọdun mẹta sẹyin, Gomina Akinwunmi Ambọde so pe Olorun lo ran awon lowo to fi see se. O ni awọn iṣẹ ribiribi naa ko seyin re.

Ambode sọro yii nibi isin idupẹ pataki ti wọn ṣe l’Alausa, ni ojo Aiku, Sannde, ọse yii.

O so pe, “Pẹlu ipo ti ipinlẹ Eko wa loni-in, o fihan pe Ọlọrun n ba wa lọwọ si gbogbo erongba wa, agbekale ati ipinnu wa lati mu ki nnkan derun fun awon araalu ti a n sejoba le lori, eyi to n yọri si daadaa fun ipinlẹ wa.

“Lọtunla yii lo maa pe ọdun mẹta ti ijọba wa ti bẹrẹ iṣẹ, ko si ọna to tun daa to lati ṣe ayẹyẹ yii ju bi a ti ṣe ko ara wa jọ fun isin idupẹ lọ, nitori ko si bi a ṣe le ṣe aṣeyọri to to bayii lẹnu iṣẹ ilu ta a n ṣe bi ko ba lọwọ Ọlọrun ninu.

“Bo se wu keeyan loun kọ bi wọn ṣe n ṣeto tabi agbekale nnkan to nileewe, ko rọrun lati fẹẹ ṣe nnkan, ki tọhun ṣeto bi yoo ti ṣe e, ko gbinyanju rẹ, ki kinni naa si wa si imuṣẹ.

“Bo ba ṣee ṣe bẹẹ, to si n ṣiṣẹ lọ lai dawọ duro, a jẹ pe ẹnikan n satileyin fun iru eni bee ni, nitori aimọye eeyan lo gbero bii tirẹ, ti ero wọn ko si wa si imuṣẹ.

‘’Pẹlu bi nnkan si ṣe n lọ fun ipinlẹ Eko lọwọlọwọ lo mu wa tẹriba pẹlu irẹlẹ pe ẹnikan wa nibi kan to n faṣẹ si awọn ipinnu wa to fi n di mimu ṣẹ, a si gbagbọ pe ko si ẹlomi-in to le ṣe eyi fun wa ju Ọlọrun lọ. Eyi lo mu wa pe jọ loni-in lati dupẹ lowo re.”

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.