Aṣẹwo gun ọrẹ rẹ lọbẹ, lawọn ọlọpaa ba gba a mu

Spread the love

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja ni  awọn ọlọpaa wọ obinrin olowo nabi kan, Charity Emmanuel, lọ si kootu Majisreeti to wa ni Ikẹja, wọn ni o fi ọbẹ gun ọrẹ rẹ, Joy Emezie. Ẹsun dida ọgbẹ si eeyan lara ni wọn fi kan an.

Inspẹkitọ Benson Emuerhi ṣalaye fun kootu pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu to kọja, ni Charity huwa naa lọna Allen Avenue, Ikẹja, niluu Eko.

Emuerhi sọ pe olujẹjọ naa gun ọrẹ rẹ, Joy, eyi to da ọgbẹ si i lara. Agbefọba naa ni wahala kan lo ṣẹlẹ laarin Joy ati olujẹjọ, lojiji si ni afurasi naa fa ọbẹ yọ, to si gun un.

Digbadigba ni wọn gbe Joy lọ si ọsibitu, ti wọn si mu ẹsun iṣẹlẹ naa lọ si teṣan ọlọpaa. Ẹsun naa tako abala kan ninu ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n lo, tọdun 2015.

Ajọ Akoroyinjọ Naijiria (NAN), jabọ pe Charity loun ko jẹbi ẹsun naa pẹlu alaye.

Adajọ Olufunkẹ Sule-Amzat faaye beeli ẹgbẹrun lọna aadọta Naira silẹ fun un, pẹlu oniduuro kan niye kan naa.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keji, lo sun igbẹjọ mi-in si.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.