Aṣe loootọ ni pe awo egungun lobinrin le ṣe

Spread the love

Awọn olorin wa maa n kọrin pe, “Awo egungun lobinrin le ṣe, awo gẹlẹdẹ lobinrin le mọ, bobinrin foju kan oro, oro yoo gbe e!” Ṣe ni atijọ, ati titi di isinyii naa, ni awọn ilu kọọkan, ko si obinrin ti i foju kan oro, nitori awo awọn ọkunrin ni. Bi obinrin ba foju kan oro, iyẹn ni pe bi obinrin ba ri ooṣa oro, ọjọ naa ni yoo ri ile aye mọ. Idi ti eleyii fi ri bẹẹ ni pe awo ti awọn ọkunrin fi n ṣe eto ilu ni, awo ọdaju ti wọn fi n fiya jẹ ẹlẹṣẹ, ti wọn si fi n ṣe awọn etutu to ba le ni. Nidii eyi, bi wọn ba ri obinrin nibẹ, nitori pe wọn mọ pe obinrin ko ni gongo to le fi ọrọ pamọ si titi, wọn yoo pa a ni, ki aṣiri naa ma baa tu. Amọ bo ba jẹ ti eegun ni, aa, bi eegun paapaa ko ba ri obinrin, ko ni i jade, nitori awọn obinrin ni yoo ṣe ariya fun un. Bẹẹ naa si ni gẹlẹdẹ, awọn obinrin ni wọn yoo jọ ṣe ẹfẹ, ti wọn yoo si jọ yi ilu po. Ohun ti wọn n sọ nibẹ ni pe awọn kinni kan wa ti obinrin ko gbọdọ tẹri si, bo ba tẹri si i, yoo di ewu fun un. Iyẹn ni ti obinrin kan to ti ba Aarẹ Ọbasanjọ ṣiṣẹ nilẹ yii, obinrin ọmọ Ibo ti wọn n pe ni Oby Ezekwesili. Ọmọwe ni o, o mọwe daadaa, bẹẹ lo mọ nipa eto iṣakoso, nibi ti ọpọlọ rẹ si ṣiṣẹ de, o ti ba wọn ṣiṣẹ ni banki agbaye. Ko si tabi ṣugbọn nibẹ bi iru obinrin yii ba ribi de ipo aarẹ orilẹ-ede yii, wọn yoo ṣe daadaa ju awọn ti wọn n pariwo wọn loni-in yii lọ. Ṣugbọn ayangbẹ aja ni ọrọ wọn, ayangbẹ aja dun pupọ, ki leeyan yoo waa maa jẹ ki aja too gbe, nitori aja ki i gbẹ bọrọ, yoo maa ṣọra sinu ina ni. Oby jade pe oun yoo du ipo aarẹ loootọ, o si ni ki awọn eeyan dibo foun, oun yoo ṣe daadaa. Ṣugbọn ẹnu lasan lobinrin yii fi sọ ọ, boya o ṣe kampeeni diẹ ni Abuja, o si de ilu kan tabi meji ni ilẹ Ibo, ko tilẹ gba ọna ilẹ Yoruba kọja rara. Bẹẹ ni ko le dele ọba ko le dele ijoye, ko si le ṣe ipolongo ita-gbanba kan, nitori ko jọ pe ẹgbẹ oṣelu rẹ ni kọbọ lapo wọn. Nigbẹyin, obinrin naa sọ lọsẹ to kọja pe oun ko ṣe mọ o, oun ti juwọ silẹ, kawọn ti wọn lowo, ti wọn si lagbara, maa ṣe kinni ọhun lọ. Ọrọ naa ki i ṣe ọrọ ẹrin, nitori ohun to tumọ si ni pe owo ni wọn fi n ṣe oṣelu ilẹ yii, ẹni ti ko ba lowo lọwọ ko le debi kan. Bẹẹ, iyẹn ko ni i jẹ ki awọn ọlọpọlọ ti wọn nimọ da sọrọ oṣelu ilẹ wa, awọn wuligansi, awọn olowo ojiji, awọn oniṣowo to n wa owo kun owo, awọn naa ni yoo maa ṣe oṣelu ilẹ yii lọ. Ewu gidi si ni fun orilẹ-ede yii lọjọ iwaju, afi ki Ọlọrun yọ wa o.

 

 

(107)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.