Nitori idajọ ile-ẹjọ, oludije APC di meji ni Kwara

Spread the love

Lẹyin idajọ to kede Ishola Balogun-Fulani gẹgẹ bii alaga APC, awọn oludije ẹgbẹ naa ti di meji bayii pẹlu bi wọn ṣe ṣe agbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹwaa ti yoo ṣakoso ipolongo ibo fun Kayọde AbdulWahab Ọmọtoshẹ.

Ọmọtoshẹ lawọn igun Balogun-Fulani fa kalẹ ni oludije fun ipo gomina, ṣugbọn Abdulrahman Abdulrasak lo n ṣoju igun ti Bashiru Bọlarinwa.

Balogun-Fulani ni gbogbo awọn ọmọ igbimọ naa ni wọn to gbangba-a-sun lọyẹ lati ri i pe oludije funpo gomina tawọn yan atawọn oludije fun ipo mi-in jawe olubori lọdun 2019.

Bakan naa lo tun gbe igbimọ apẹtu-saawọ ti yoo pẹtu sawọn ọmọ ẹgbẹ to n fapa-janu kalẹ.

Awọn ọmọ igbimọ ipolongo to gbe kalẹ naa ni: Alhaji Jimoh Balogun to jẹ ọga agba, Oloye Christopher Ayẹni, (Kwara South), Alhaji Ali Baba (Kwara Central), ati Alhaji Othman Mohammed fun ẹkun Kwara North.

Awọn to ku ni: Alukoro, Dokita Dele Kayọde (DELKA), adari obinrin, Hajia Tọlani Ibrahim, alakooso eto-isuna, Hajia Jibikẹ Alabi, adari ọdọ, AbdulMumini Mohammed, alakooso eto aabo, Alhaji Yusuf ati Raheem Bello.

Balogun-Fulani ni idajọ ile-ẹjọ naa ti paṣẹ fajọ INEC lati ma ba igun Bashiru Bọlarinwa ṣiṣẹ, ṣugbọn igbimọ toun atawọn oludije tawọn yan ni ojulowo.

Latigba tidaajọ naa ti waye nigun Bọlarinwa ti tako o, ti wọn si pẹjọ ko-tẹmi-lọrun.

 

 

 

(16)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.