2019: Ọwọ awọn oloṣelu ni aṣeyọri idibo yii wa – Agbaje

Spread the love

Kọmisanna fajọ eleto idibo nipinlẹ Ọṣun, Ọluṣẹgun Agbaje, ti sọ pe ọna abayọ kan ṣoṣo si wahala to maa n ṣẹlẹ lasiko idibo lorileede yii ni kawọn oloṣelu dẹkun fifi ipa wa ipo.

 

Agbaje sọrọ yii fun akọroyin Alaroye lọsẹ to kọja. O ni awọn oloṣelu ni wọn maa n pọnmi oke ru todo, ti wọn si maa n sọ ajọ eleto idibo di alaimọ-ọn ṣe loju awọn ara ilẹ okeere.

 

O fi kun un pe rira ibo, lilo awọn tọọgi lati da ibudo idibo ru, gbigbe iroyin-eke kaakiri ọdọ awọn araalu lati le jẹ ki wọn korira ẹgbẹ oṣelu mi-in wa lara nnkan ti ko jẹ ki eto idibo orileede yii niyi loju awọn awujọ agbaye.

 

Agbaje, ẹni to ni ko si ootọ kankan ninu ọrọ ti awọn ẹgbẹ oselu kan sọ laipẹ yii pe ajọ eleto idibo ti n ko kaadi idibo alalopẹ to ṣẹku lọdọ wọn fun awọn oloṣelu kan, o ni kaadi yii ko ṣe e ba eeyan gba.

 

O ni ko si bi ẹni ti ki i ṣe pe oun lo forukọ silẹ ṣe le lo kaadi yẹn, idi si niyi ti ajọ eleto idibo ṣe n fọnrere lojoojumọ pe kawọn araalu lọ sibudo ti wọn ti n gba kaadi naa lati gba a.

 

Agbaje ni kaadi idibo nikan ni agbara tawọn araalu ni, ko si si anfaani fun ẹnikẹni ti ko ni kaadi lati yan ẹni to ba wu u latinu ẹgbẹ oṣelu to wu u sipo kankan lorileede yii nigba tasiko ba to.

 

Nipinlẹ Ọṣun, kọmisanna yii ni eeyan miliọnu kan o le igba (1,254,467) ni wọn ti gba kaadi alalopẹ ninu awọn miliọnu kan aabọ o le diẹ (1,681,930), ti wọn foruko silẹ fun kaadi naa.

 

O waa rọ awọn ẹẹdẹgbẹfa o din diẹ (427,463), ti wọn ko ti i gba kaadi ọhun lati tete lọọ ṣe bẹẹ, ki wọn ma baa sọ anfaani lati dibo lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ati ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii, nu.

 

Bakan naa lo rọ awọn oloṣelu lati ma ṣe ri idibo to n bọ yii bii afipa-gba, ki wọn bọwọ fun ifẹ awọn araalu, ki wọn mọ pe ko sibomi-in ti wọn le pe ni orileede wọn ju Naijiria lọ, ki wọn si jẹ ki idibo to n bọ yii tun orukọ orileede wa ṣe loju awọn orileede agbaye.

 

 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.