2019: Ọọdunrun ọmọ ẹgbẹ APC darapọ mọ PDP niluu Jẹbba

Spread the love

O kere tan ọọdunrun (300), awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), niluu Jẹbba, nijọba ibilẹ Moro, lo ju igbalẹ wọn danu lọjọ Abamẹta, Satide, ti wọn si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Awọn to darapọ mọ ẹgbẹ PDP ọhun lẹgbẹ naa gba wọle nibi ayẹyẹ pataki kan ti wọn ṣe lati bu ọla fun Igbakeji Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Kwara,  Mathew Ọkẹdare, to n ṣoju ẹkun Lanwa/Ejidongari.

Awọn to darapọ naa ni ohun to mu awọn ṣe bẹẹ ni idari rere ti aṣofin naa n ṣe fawọn araalu to n ṣoju.

Adari ẹgbẹ awọn ọdọ, Jebba Youth Vanguard, Ọlanrewaju Jamiu, sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ti jẹ ọmọ ẹgbẹ APC tọkantọkan tẹlẹ, ṣugbọn awọn ko le tọka si anfaani kankan tawọn ri gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ.

Jamiu ni ko si eyi ti ẹgbẹ yii mu ṣẹ ninu gbogbo ileri ti ṣe fawọn araalu lasiko ibo ọdun 2015, dipo ki nnkan si yipada si daadaa, niṣe lo tun n buru si i lojoojumọ.

Bakan naa ni adari ẹgbẹ APC Labour Camp, niluu Jebba, Ọgbẹni Godwin Pius, sọ pe Ọkẹdare ko figba kankan ta awọn nu rara, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu alatako lawọn n ṣe tẹlẹ.

O kede atilẹyin wọn fun ẹgbẹ PDP lati jawe olubori ninu idibo ipinlẹ ati ti ijọba ạpapọ lọdun 2019.

Igbakeji Abẹnugan ile aṣofin Kwara, Ọnarebu Mathew Ọkẹdare, to gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun naa wọle sọ pe igbesẹ to dara ni wọn gbe nipa didarapọ mọ ẹgbẹ to n ṣejọba. O ni wọn ko ni i kabaamọ pe wọn yan PDP laayo.

 

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.