2019: Atunwa di kolẹ-kolẹ sigboro Ilọrin, ṣugbọn wọn ni oṣelu lo fi ṣe

Spread the love

Awọn araalu ti ni ọgbọn oṣelu lasan ni eto gbaluu-mọ ati kolẹ-kodọti ti oludije gomina ẹgbẹ PDP, Rasak Atunwa, gbe kalẹ lọsẹ to kọja.

Wọn ni nibo lọkunrin naa wa lati ọdun mẹta sẹyin to waa jẹ pe nigba ti idibo ku oṣu meji lo sọ ara rẹ di akolẹ igboro to waa n ko ilẹ kaakiri.

Ọgbẹni Raheem Abdulkameen to n gbe n’Ita Kudimọ, niluu Ilọrin, nibi ti oludije naa ti feto ọhun lọlẹ ni ilẹ ti ọkunrin naa n ko ọhun ko ṣẹṣẹ debẹ, oun gan-an funra rẹ ko ṣẹṣẹ maa ri  bawọn eeyan ṣe n da ilẹ kaakiri igboro, nitori naa, ko ma mu awọn lọbọ rara.

O nijọba ati ileeṣẹ to n kolẹ nipinlẹ Kwara ni wọn ko ṣe ojuṣe wọn bo ṣe yẹ, idi niyi ti idọti fi ga gelemọ si aarin ilu.

Lọsẹ to kọja ni Atunwa ṣefilọlẹ eto to pe ni Atunwa Evacuation Project. Erongba rẹ ni lati ko gbogbo ilẹ to wa n’ile Baba Olobi, lagboole Alapa, n’Ita Kudimọ, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilorin.

Nibẹ lo ti tun ṣeleri fawọn araadugbo naa lati pese ile-igbọnsẹ igbalode atawọn ọsibitu to dara toun ba de ipo gomina.

Inu awọn ara Ita Kudimọ dun si eto kiko idọti ti wọn lo le ṣe jamba fun ilera awọn to n gbe agbegbe naa.

 

 

 

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.