2019: Afẹnifẹre tako ara wọn nitori Buhari ati Atiku

Spread the love

Pẹlu bi idibo aarẹ lorilede yii ṣe ku ọsẹ kan ati ọjọ bii meloo kan, ẹnu awọn Afẹnifẹre, ẹgbẹ Yoruba ko ko lori ẹni ti wọn yoo ṣatilẹyin fun ninu awọn to n dupo aarẹ.

 

Ẹgbẹ Afẹnifẹre, eyi ti Sẹnetọ Ayọ Fasanmi n dari pẹlu awọn oloṣelu ọmo Yoruba kan ni wọn ko ara wọn jọ si gbọngan ICC to wa ninu ogba Fasiti Ibadan (UI), ti wọn si pinnu lati ṣatilẹyin fun Aarẹ Buhari ati Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ninu idibo aarẹ ti yoo waye lopin ọsẹ to n bọ yii.

 

Diẹ ninu awọn ọba ilẹ Yoruba bii Ataoja Oṣogbo, Akirun ti Ikirun, Olokuku ti Okuku, Oniyin ti Iyin-Ekiti pẹlu awọn eekan ilu bii Ọmọwe Yẹmi Ẹlẹbuibọn ti i ṣe Araba ilẹ Oṣogbo ati alaga ẹgbẹ awọn awakọ ero (NURTW) ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Abideen Ọlajide (Èjìogbè), ni wọn wa nibi ipade ọhun.

 

Nigba to n dabaa pe ki ẹgbe Afẹnifẹre fi Aarẹ Buhari ṣe aayo wọn laarin awọn akẹgbẹ ẹ ti wọn jọ n dupo ninu idibo ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun (16), oṣu keji, ọdun yii, Sẹnetọ Ọlabiyi Durojaye sọ pe “nitori pe erongba ẹgbẹ APC to n ṣejọba lọwọ mu igbaye-gbadun aaraalu lọkun-un-kundun, o si ba ba ifẹ ọkan Yoruba ati ilana iṣejọba Awolọwọ mu yatọ si tawọn ẹgbẹ oṣelu yooku, a ti pinnu lati dibo fun Buhari ati Ọṣinbajo pẹlu gbogbo awọn oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC paapaa, Buhari ati Ọṣinbajo gẹgẹ bii aarẹ ati igbakeji.”

 

Awọn to gba aba ọhun wọle ti gbogbo wọn fi sọ ọ di ipinnu wọn ni Oloye Tajudeen Olusi, Alagba Yẹmi Alade, alaga Afẹnifẹre l’Ekiti, Ọjọgbọn Bayọnle Adémodi (Ondo); igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Sooko Adewọyin (Ọṣun); Iyalọja Yoruba, Alaba Lawson ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Ṣugbọn igun awọn Afẹnifẹre keji sọ pe iranu lasan lawọn to ṣe eleyii n ṣe nitori ọmọ Yoruba gidi kan ko jẹ sọ pe Buhari loun fẹẹ dibo toun fun.

 

Agbẹnusọ awọn Afẹnifẹre yii, Ọgbẹni Yinka Odumakin sọ ninu ifọrọwerọ ori foonu pẹlu akọroyin wa pe “ẹgbẹ Afẹnifẹre ko ti i jẹjẹẹ atilẹyin fun oludije dupo aarẹ kankan ninu idibo to n bọ yii. Awọn tẹ ẹ ri yẹn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wa. Tinubu lo kan ko wọn jọ nitori ọrọ oṣelu lasan. Ẹni kan ṣoṣo ta a mọ ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre ninu gbogbo awọn to wa nipade yẹn ko ju Sẹnetọ Ayọ Fasanmi lọ, awọn gan-an si ti wa sipade tipẹ.

 

“Afenifere lo mọ bi Tinubu ṣe di gomina ipinlẹ Eko lọdun 1999. A o mọ iru eeyan to jẹ nigba yẹn. Ṣ̣ugbọn bo ṣe di gomina tan lo kọyin si ẹgbẹ yii. Oun lo lọọ ko awọn eeyan yii jọ pe ki wọn maa pe ara wọn l’Afẹnifẹre. Awa o ni ki wọn ma ko ara wọn jọ fun Buhari, ṣugbọn ki wọn pera wọn lorukọ mi-in.

 

“Ko si ẹni to fẹ iran Yoruba fun rere ninu wọn, afẹnifẹbi ni wọn. Abi ki lẹ gbọ ti ẹnikẹni ninu wọn sọ nigba ti awọn Fulani pa Yoruba rẹpẹtẹ n’Ile-Ifẹ lọjọsi, ti Buhari tun fi ọlọpaa ko awọn ọmọ Yorunba lọ si Abuja? Ṣebi awa yii la n sare kiri nigba naa. Njẹ ẹnikankan gbọ ki Tinubu gan-an sọ nnkan kan nigba naa”?

 

Lagbara Ọlọrun, nigba to ba maa fi di Mọnde to n bọ yii, gbogbo aye lo maa mọ ibi ti awa Afẹnifẹre n lọ lori idibo aarẹ ọdun 2019 yii.

 

Gẹgẹ bii iwadii Alaroye ṣe fidi ẹ mulẹ, ipade ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni igun awọn Afẹnifẹre yii pẹlu igun kan lara awọn ẹgbẹ Arẹwa, nilẹ Hausa, atawọn Ohaneze, nilẹ Igbo, yoo ṣepade lati pinnu lori oludije ti wọn yoo ṣatilẹyin fun ninu idibo aarẹ to n bọ. Ilu Abuja nipade ọhun yoo ti waye, o si ṣee ṣe ko jẹ Atiku Abubakar ni wọn yoo kede gẹgẹ bii oludije dupo aarẹ ti wọn yan laayo.

 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

 

Saheed fi fisa lu Samson ni jibiti, ladajọ ba ni ko lọọ ṣe Falẹntain lẹwọn

 

Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Saheed Ademọla pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun yii, lori ẹsun ole-jija ti wọn fi kan an.

 

 

 

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.