• Ṣe bẹ ẹ ri Ọbanikoro to dọmọ Buhari

Spread the love
  • O daju pe bi wọn ba n ka awọn ti wọn n ṣiṣẹ julọ fun Buhari lati di aarẹ lẹẹkeji bayii, ipo pataki ni wọn yoo ka Musiliu Ọbanikoro si. Oloṣelu ni Musiliu Ọbanikoro, bẹẹ lo si ti di ipo nla daadaa mu nilẹ yii ri, ko si sohun to buru nibẹ bo ba ṣiṣẹ fun Buhari. Ṣugbọn kọkọrọ kan wa nibẹ to ba eyin aja jẹ, iyẹn naa ni pe ole akowojẹ ni Ọ Buhari mọ, awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ mọ, EFCC si ti gbe ọkunrin yii laimọye igba, orukọ rẹ ko si ti i kuro ninu iwe wọn. Koda, titi di bi a ṣe n wi yii ni ọkan ninu awọn ti wọn jọ kowo jẹ yii, Ayọdele Fayoṣe, ṣẹṣẹ de nitimọle awọn EFCC, bẹẹ ẹṣẹ kan naa ni wọn ṣẹ, ole kan naa ni wọn jọ ja, owo kan naa ni wọn jọ ko jẹ. Eleyii fihan pe ọrọ ti Oshiomhole sọ pe beeyan ba ti di ọmọ APC, o ti bọ ninu ijiya ẹṣẹ rẹ, ododo gbaa ni. Nigba ti awọn ti wọn ba ilu jẹ ba sa si ẹyin Buhari lati maa ba a ṣiṣẹ, ti ko si sẹni to le sọrọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ, apẹẹrẹ bẹẹ ko dara. Bi a ba fẹẹ gbogun tiwa ibajẹ, ka fi gbogbo ara ṣe e, ka mu gbogbo ẹlẹṣẹ, ka si fi oju wọn han lawujọ bii oju aṣebi. Ko si ijiya to dara to ki aye ri aṣebajẹ nipo ẹni ti ko jẹ nnkan kan mọ, ki gbogbo agbara ati iyi ẹni bẹẹ wọmi lọ. Amọ nigba ti eeyan ba ṣe ibajẹ, to ko owo buruku jẹ, to jẹ oun naa lo n jokoo sipo awọn ọlọla, to jẹ oun lo n tẹle olori ijọba kiri, eyi yoo jẹ ki awọn eeyan ti ko fẹẹ jale tẹlẹ jale ni, awọn ti wọn si ro pe iwa bii ọmọluabi lo pe julọ yoo kuro nidii ironu bẹẹ, nigba ti wọn kuku ri i pe awọn to jale lo n ri ipo gidi mu lawujọ. Bi a ba n ṣe bayii, ko si bi ijọba tabi eto oṣelu wa yoo ṣe dara. Abi lọjọ wo la fẹẹ ṣe eleyii gba nitori Ọlọrun.

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.