Ṣugbọn kin ni Atiku paapaa n wa lọ si Amẹrika o

Spread the love

Beeyan ba fẹẹ beere ko beere, ko si ohun to buru ninu ibeere o. Kin ni Atiku n wa lọ si Amẹrika? Ki lo de ti ọkunrin naa bẹrẹ wahala to pọ to yii, ti ọrọ naa fi n di ariwo pe dandan ni ko lọ si Amẹrika. Ṣe nitori ohun ti awọn APC n sọ ni ati nitori ẹjọ ti wọn ni wọn ba awọn ọrẹ rẹ to wa lọhun-un ṣe. Ṣe nitori pe wọn ni wọn n wa a ni, abi nitori pe o di dandan fun un lati lọ si Amẹrika, ki awọn yẹn le fọwọ si i pe awọn fẹ ko di aarẹ Naijiria ni. Eyi o wu ko jẹ nibẹ, idaamu ati wahala ti Atiku ko ba ara rẹ nitori ọrọ Amẹrika yii ko nitumọ gidi kan. Ṣe Amẹrika lọmọ Naijiria ti yoo dibo ni, abi Amẹrika lo n kọnturoolu ijọba Naijiria. Awọn ohun kan wa to yẹ ki ọmọ Naijiria ati awọn aṣaaju wa naa maa fi pọn wa le, iyẹn naa ni fifoju tẹmbẹlu ẹni to ba ni awa naa ko jẹ kinni kan. Nibo ni Atiku wa nigba ti olori ilẹ Amẹrika n rọjo eebu le wa lori, to n pe awọn eeyan wa ni oriṣiiriṣii orukọ, to si n bu wa bii ẹni pe ọmọ ile rẹ la jẹ. Nibo ni Atiku wa nigba ti Trump, olori wọn l’Amẹrika yii, bu Buhari pe ko lẹmi-in ninu mọ nitori pe iyẹn lọ si orilẹ-ede wọn lati lọọ ṣe abẹwo. Ẹni to bu wa pe ti awọn ọmọ Naijiria ba ti wọ Amẹrika, wọn ki i fẹẹ pada sinu ahere ti wọn ti wa mọ; odidi orilẹ-ede Naijiria lo n pe ni ahere yẹn. Ki waa ni Atiku n wa lọ sibẹ, ki lo fa ariwo, ki lo fa kukukẹkẹ iranu. Nigba mi-in, awọn oloṣelu yii paapaa ki i mọ ohun to tọ ati ohun ti ko tọ, wọn yoo maa sare kiri ibi ti ko yẹ ki wọn de, wọn yoo fi awọn araalu tiya n jẹ silẹ, ṣe wọn ti mọ pe nigbẹyin, irọ nla lawọn yoo pa fun wọn. Ilu la o wa nigba ti Atiku ba lọ si Amẹrika to ba de, awọn Lai Muhammed leeyan yoo si fa a le lọwọ, wọn yoo sọ aṣiri gbogbo to wa nibẹ, ati ohun to ṣe lọhun-un ati eyi ti ko ṣe. Yẹyẹ to wẹwu to roṣọ!

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.