Ṣugbọn ka ma purọ, o yẹ koju ti ẹgbẹ APC

Spread the love

Ọlọrun lo mọ iru ẹjẹ ti wọn fi da awọn aṣaaju ẹgbẹ APC, o si jọ pe iru ẹjẹ naa lo wa lara ọpọ ọmọlẹyin wọn. Bi wọn n na wọn lọ, ti wọn n ku lọ bayii, wọn yoo si maa leri, wọn yoo maa janu. Ailojuti lo si n fa iru nnkan bẹẹ yẹn o. Amọ bi o ba n wi, isọkusọ ni wọn yoo maa sọ si ọ, ko si si orin meji naa ti wọn mọ-ọn kọ ju lati ba ọ lorukọ jẹ lọ, wọn yoo ni o ti gbowo lọwọ PDP ni, bẹẹ wọn mọ pe awọn ni awọn ṣe ohun ti ko dara o. Abi eti wo lo n gbọ ọ, pe Gomina Arẹgbẹṣọla ṣe ijọba fun ọdun mẹjọ, o waa di igba to fẹẹ gbejọba silẹ, ẹni kan ti wọn ni alajoota ni waa jade, o si na ẹgbẹ oṣelu rẹ bẹẹ yẹn. Ohun yoowu ti wọn ba gbe jade lẹyin eyi ko ni koko kan mọ, koda bi wọn ba wọle, aye yoo ti mọ pe ojooro ati eru ni wọn ṣe, nitori PDP ti wọle tẹlẹ. Amọ ohun ti awọn ara ilu sọ fun Arẹgbẹ ati ẹgbẹ rẹ ni pe awọn ko fẹ bi wọn ti ṣejọba le awọn lori, ijọba wọn ko mu itura kan dani fun wọn ni. Awọn naa yoo wa nibi kan ti wọn yoo maa sọ pe alaimoore lawọn eeyan Ọṣun o, bẹẹ ki i ṣe pe awọn yẹn lọgbọn kan to ju tawọn eeyan naa lọ, awọn n sọ ọ nitori ariwo eke ti wọn n gbọ lori beba ati lori redio ni, a si tun fi awọn ti wọn n jẹ ninu ohun to n lọ nibẹ. Awọn ara Ọṣun ke to, wọn pariwo to, pe iya n jẹ awọn, abi nigba ti oṣiṣẹ ba ṣiṣẹ titi ti ko ri owo oṣu gba, ti awọn oniṣowo ati kọntirakitọ Ọṣun ko ri iṣẹ gba, to jẹ awọn ti wọn wa l’Ekoo ni wọn waa gbe iṣẹ fun, to jẹ gbogbo ohun ti Arẹgbẹ yoo ba ṣe, Eko ni wọn yoo ti mu awọn ti yoo ṣe e wa. Ki waa ni ki awọn eeyan yii ṣe, ṣe ki wọn maa pọn ọn le ni abi ki wọn maa dọbalẹ ki i. Nigba ti wọn mọ pe ko si ohun ti awọn le ṣe ni wọn ṣe n tan wọn, ti wọn n pariwo pe ohun ti wọn ṣe lo dara julọ. Ṣugbọn nigba to to akoko ibo, wọn fi han wọn pe awọn ki i ṣe omugọ, dida lo da ti ọmọ dẹgbẹẹ ni. Eeyan ko si le bu wọn, ohun ti a n pe ni ijọba dẹmokiresi niyi. Ṣebi awọn naa ni wọn gbe Arẹgbẹ yii kan naa wọle lọjọsi, ti wọn le tori rẹ ku nigba ti ko si nile ijọba, bo ṣe ṣejọba rẹ ko tẹ wọn lọrun ni, iyẹn ni wọn ṣe fibo dojuti i. Ẹkọ ni ki eleyii jẹ fun ẹgbẹ APC ni gbogbo ipinlẹ to ku. Bi wọn ba n leri kiri pe ko si bi awọn ko ṣe jẹ, ti wọn n tan ara wọn pẹlu ariwo eke lori Facebook ati beba, abuku ti yoo maa kan wọn kaakiri niyi o. Ẹ tete, ẹ yaa feyi kọgbọn!

 

(62)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.