Ṣugbọn ẹsin alatọsi ko si lọwọ okobo o

Spread the love

 

Ohun ti Yoruba n pe ni “ẹsin” ni yẹyẹ, bi wọn ba n fi eeyan ṣe ẹsin, wọn n fi i ṣe yẹyẹ naa ni. Okobo ni ẹni ti ko le ṣe, ti ko le ba obinrin ni aṣepo, ti ko si le bimọ nigba ti ko le ṣe. Alatọsi ni ẹni to ko arun atọsi, arun ti wọn maa n ko nibi ibalopọ ni, bi atọsi ba wa lara obinrin kan ti ọkunrin mi-in ba ba a ṣe, oun naa yoo ko kinni ọhun ni, o di alatọsi niyẹn. Arun gbajumọ ni wọn n pe atọsi, nitori arun ti ọkunrin to da pe maa n ko ni. Bi ọkunrin kan ba waa ko atọsi, ti okobo ti ko le ṣe rara ba waa gbe ilu jade to n fi ẹni naa ṣe ẹsin, ṣe ẹ mọ pe okobo lo n kọja aaye ara rẹ. Bi ọrọ Buhari ati Jonathan ti ri niyẹn. Jonathan ko ṣe daadaa, iwa ibajẹ ati ole pọ ninu ijọba rẹ, ṣugbọn tirẹ tun fẹrẹ daa ju ti Buhari yii lọ. Nigba ti Jonathan n lọ, o gbe orilẹ-ede Naijiria fun wa bo ṣe ba a, ko si ẹlẹyamẹya, bẹẹ ni ko gbe ẹya kan lori ẹya mi-in, ko si gba awọn eeyan rẹ laaye lati maa paṣẹ awọn ẹya mi-in kiri. Ole jija to n lọ ninu ijọba yii naa ko kere, o pọ gan-an. Nigba ti ijọba ba bọ lọwọ Buhari, ti awọn mi-in ti wọn fẹẹ fori sọle pe oun lo dara ju ni gbogbo aye ba gbọ awọn owo ti wọn ko jẹ labẹ rẹ, ati awọn iwa ibajẹ buruku ti wọn n hu lọ lọwọlọwọ bayii, ko ma jẹ igba yẹn gan-an ni wọn yoo binu bẹ somi. Awọn ohun to n ṣẹlẹ laye Jonathan ko yipada laye Buhari, ohun to yipada bayii jọ pe ọtọ lawọn ti wọn kowo jẹ laye Jonathan, ọtọ lawọn ti wọn ko owo jẹ ti wọn si n jale laye Buhari, aṣiri wọn yoo tu nigba to ba ya. Ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, nitori pe Jonathan ko ṣe daadaa ni ọmọ Naijiria ṣe dibo fun Buhari, ṣugbọn ko si iyatọ kan to ṣee tọka si lẹyin ti a dibo fun un. Ohun ti awọn tilẹ ni to buru ni irọ pipa, ko si ijọba kan to fẹran irọ to eyi ti a wa ninu rẹ yii: wọn n purọ, wọn n ṣeke, wọn n jale. Kin ni ijọba Buhari waa fi san ju ti Jonathan lọ? Ki waa ni awọn ọmọ Aarẹ bẹrẹ si i fi Jonathan ṣe yẹyẹ pe o gbe iwe irọ jade si? Bi ẹ ba ti ri wọn ẹ sọ fun wọn pe ẹsin alatọsi ko si lọwọ okobo, ole gbe e, ole gba a naa ni gbogbo wọn.

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.