Ṣugbọn aṣeju Amosun naa papọju

Spread the love

Bi a ba ni Oshiomhole ko lo ofin to lo l’Ekoo fun wọn ni awọn ipinlẹ to ku, iyẹn o sọ pe ki awọn gomina ti ọrọ kan maa joye alaṣeju, nitori ko si oore kan ti aṣeju yoo ṣe fun olowo rẹ, yoo mu un lọ si ilu abuku ni. Alaṣeju, pẹrẹ ni i tẹ, bẹẹ lo ri fun Gomina Ibikunle Amosun ni ipinlẹ Ogun, awọn ọrọ ti Oshiomhole sọ nipa rẹ ko daa. Oshiomhole ni Amosun jokoo si ile rẹ, o si ko awọn kan jọ, o si bẹrẹ si i nawọ si wọn nikọọkan, iwọ lo n lọ sile-igbimọ aṣofin l’Abuja o, iwọ ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun nibi ni tiẹ, emi ati iwọ la jọ n lọ si ile-igimọ aṣofin agba, bẹẹ lo si dide to na ọwọ Akinlade soke, to ni, gomina wa niyi ni 2019, oun la maa gbe ijọba Ogun le lọwọ. Bawo leeyan ṣe n ṣe yẹn? To ba jẹ bi dẹmokiresi ti ri ni gbogbo aye niyi, awọn ọbayejẹ oloṣelu Naijiria yii ko ni i maa sa lọ si Amẹrika lati lọọ gba itọju nibẹ tabi lati lọọ ko owo ti wọn ba ji ko pamọ sibẹ. Ṣebi nitori pe dẹmokiresi wa lọdọ tiwọn ni. Ko si si ohun ti wọn n pe ni dẹmokiresi to ju ka tẹle ofin lọ. Ẹgbẹ oṣelu ni i paṣẹ lọdọ wọn, ki i ṣe ki ẹni kan wọle ibo tan, ko sọ ara rẹ di Ọlọrun. Bi wọn ba yan ẹni kan sipo, tọhun yoo wa nipo naa titi ti saa rẹ yoo fi tan, yoo dojukọ iṣẹ ilu, yoo si ṣe iwọnba to ba le ṣe, iṣẹ to ba ṣe lawọn eeyan yoo si fi maa ranti rẹ. Bi saa rẹ ba ti tan, yoo maa lọ jẹẹ ni, awọn ẹgbẹ ni wọn yoo si yan ẹlomi-in funra wọn. Ṣugbọn ti awọn eeyan wa ko ri bẹẹ, bi wọn ba lo saa tiwọn tan, wọn yoo fi ọmọọṣẹ wọn kan sibẹ, ki wọn le tubọ maa paṣẹ fun un, ko si jẹ awọn ni wọn yoo maa ṣejọba ipinlẹ naa titi, ki wọn le maa ko owo wọn jẹ, ki wọn si le maa ṣe aburu to ba wu wọn, ko ma si si ọna ti aṣiri wọn yoo fi tu tabi ti araalu yoo fi mọ ohun to ba n lọ, nigba to ba jẹ awọn ni wọn n ṣejọba lọ. Ohun ti Amosun fẹẹ ṣe ree, to jokoo si oju kan to n naka kiri pe lagbaja ni yoo lọ sile-igbimọ aṣofin, tamẹdun ni yoo di gomina. Oun ti gbagbe pe ohun to da wahala silẹ laarin Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Akinrogun Ṣẹgun Ọṣọba ree, nigba ti Tinubu fi tipatipa gbe Amosun lori awọn eeyan Ọṣọba gbogbo ti wọn fẹẹ ṣe gomina. Ki waa lo n ṣe oun naa to n fapa-janu, to n leri pe oun yoo di waya NEPA mu si, nigba to jẹ iru eto to gbe oun naa depo niyẹn. Baye ṣe ri lẹ ri yii o, awọn apani ki i fẹ ki ẹnikẹni mu ida kọja nipakọ awọn, wọn yoo bẹrẹ ariwo ni. Ẹ sọ fun maanu yii ko ṣe suuru o, bi bẹẹ kọ, abuku ti yoo kan an yoo ju eyi to wa nilẹ yii lọ o.

(63)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.