Ṣugbọn ṣe Fayoṣe lo ran awọn tọọgi yii niṣẹ ni

Spread the love

Aworan fidio naa ko dun mọ ẹnikẹni ninu, afi ẹni to ba fẹran wahala nikan, ati awọn ti wọn ko ba fẹ rere fun Ekiti. Aworan awọn tọọgi ti wọn n lọọ ya posita ti wọn ya Kayọde Fayẹmi si kaakiri ni. Bi awọn kan ti n ya aworan naa, bẹẹ ni awọn kan n fa patako ti wọn lẹ ẹ mọ ya. Dajudaju, ki i ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ APC lo ṣe eleyii, bẹẹ ni yoo ṣoro ki ọmọ PDP kan too jade lọọ ṣe iru iranu bẹẹ ki awọn Fayoṣe to n ṣe gomina ma mọ si i. O ṣee ṣe ki wọn purọ tabi ki wọn fi ọrọ bo o mọlẹ pe ko le ri bẹẹ, ṣugbọn bo ṣe ri niyẹn. Igba kan wa ti awọn Fayẹmi yii kan naa ṣe bẹẹ fun Fayoṣe ni ọdun 2014, ti wọn n ya posita ẹ, ti wọn n fọ pako to ya fọto ara rẹ si. Niṣe ni Fayoṣe figbe bọnu nigba naa, gbogbo aye lo si n pariwo, ti wọn n da Fayẹmi lẹbi. Ohun tawọn eeyan si ṣe n pariwo naa ni pe iru iwa bẹẹ ki i ṣe ti ọmọluabi, ko yatọ si iwa ẹranko! Iyẹn lo ṣe yaayan lẹnu pe bi Fayẹmi ati awọn tọọgi kan ba huwa ẹranko nigba naa, ṣe o waa yẹ ki wọn tun ba iru iwa bẹẹ lọwọ Fayoṣe ni. Ṣe ẹ ri awọn oloṣelu yii, wọn ko ni iwa daadaa rara. Ija ti wọn maa n ba ara wọn ja, bii ija iku, bii ki wọn ba ti ara wọn jẹ, bii ki wọn ṣe ara wọn leṣe ni. Wọn yoo si sọ fun yin pe awọn fẹẹ waa sin yin ni. Ṣe awa ni wọn n waa sin ni abi wọn fẹẹ waa sin ara wọn, abi wọn fẹẹ waa lo owo araalu, wọn fẹẹ waa fi owo wa jẹun. Kin ni Fayoṣe yoo jẹ ki awọn eeyan kan maa da posita ati patako Fayẹmi wo si, nitori kin ni? Ṣe ko ma wọle yii naa, ki awọn ti wọn n ri ounjẹ jẹ lọ le maa jẹ ẹ lọ. Iwa raurau, iwa ẹranko ni jare, ki i ṣe iwa ẹnikan to da ara rẹ loju, to si mọ pe loootọ lawọn araalu fẹran oun. Ẹyin ara Ekiti, ẹ laju yin o, ki ẹ mọ ẹni ti ẹ o dibo fun loootọ, ẹ ma jẹ ki awọn eeyan yii fi burẹdi ko yin lomi ọbẹ jẹ. Ko sẹnikan to san ninu wọn o jare, ole gbe e, ole gba a. Ounjẹ ni kaluku n wa lọ sile ijọba Ekiti, iyẹn ni wọn ṣe fẹẹ pa ara wọn! Ṣiọ!

(77)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.