Ṣoyẹmi pẹ ẹ de kootu, ladajọ ba ju u sẹwọn oṣu kan

Spread the love

Ọgbẹni Kayọde Ṣoyẹmi, ẹni ọdun mejilelaaadọta, ni adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ ti ju si ẹwọn oṣu kan gbako bayii lori ẹsun pe ko yọju sile-ẹjọ lọjọ igbẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an.

 

Onidaajọ Iṣhọla Omiṣade sọ pe ijiya naa yoo jẹ ẹkọ fun awọn ti wọn ki i bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ nipa sisa fun ọjọ ti wọn ba sun igbẹjọ wọn si.

 

Ṣaaju ni agbefọba, Inspẹkitọ Christian Ọlajide, ti sọ fun ile-ẹjọ pe aago mẹsan-an lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ọdun yii, lo yẹ ki olujẹjọ farahan fun itẹsiwaju ẹjọ kan ti kọmisanna ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun pe e, ṣugbọn to kuna lati wa lọjọ yii.

 

Ọlajide ṣalaye pe iwa ti olujẹjọ hu naa lodi, bẹẹ lo si ni ijiya nla labẹ abala kẹtalelaaadoje (133), ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun ti ọdun 2002.

 

Ninu awijare agbẹjọro fun olujẹjọ, Arabinrin Innocental Akhigbe rọ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo baba agba yii, o ni ko sigba kankan ti olujẹjọ kuna lati yọju sile-ẹjọ lati ibẹrẹ igbẹjọ naa. O ni ṣe ni ọkunrin yii pẹ ẹ de kootu lọjọ naa, ki i ṣe pe ko wa rara.

 

Ṣugbọn Adajọ Omiṣade paṣẹ pe ki Ọgbẹni Ṣoyẹmi lọọ ṣọdun tuntun lọgba ẹwọn tabi ko san faini ẹgbẹrun lọna mẹwaa Naira.

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.