Ṣọọṣi ni Moses atawọn eeyan ẹ ti jale n’Ijẹbu, awọn ọlọpaa ti mu wọn

Spread the love

Awọn adigunjale mẹrin kan ti wọn yan ṣọọṣi laayo lati maa jale lagbegbe Awa Ijẹbu, nipinlẹ Ogun, lọwọ ba lọgbọnjọ, oṣu kejila, ọdun to kọja, ti wọn si ti taari wọn sẹka FSARS l’Abẹokuta.

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku to kọja yii lo fidi ẹ mulẹ pe awọn adigunjale mẹrin naa, Moses Akinniyi ti wọn n pe ni Conjour, Ogunfowokẹ Kayọde, Micheal Idogun ti inagijẹ ẹ n jẹ Headboy, ati Izunna Odah, ko niṣẹ meji ju ki wọn maa wọ ṣọọṣi jale n’Ijẹbu.

Awọn ṣọọṣi ti wọn ni wọn ti jale ri ni Love of Epistles to wa ni Agọ-Iwoye, Methodist Church, Oru Ijẹbu, bẹẹ ni wọn tun fọle kan ni Ajebọ, lagbegbe Oru Ijẹbu, kan naa.

O pẹ ti wọn ti n jale ọhun kọwọ too ba wọn lọjọ to ku ọla ki 2018 pari.  Moses, ẹni ọdun mẹtalelogoji, lo dagba ju ninu wọn. ọmọ ọdun mẹtalelogun ni Kayọde Ogunfowoke, Micheal Idogun jẹ ẹni ọdun marundinlogoji, Izunna Odah ni tiẹ ko si ju ẹni ọdun mọkandinlọgbọn lọ. Ṣugbọn gbogbo wọn ni wọn jẹwọ pe ṣọọṣi lawọn ti maa n ri nnkan ji ju, ibẹ lo si rọ awọn lọrun ju ile ti awọn n gbe lọ.

Wọn ni ọpọlọpọ ileejọsin lawọn ti ja lole lawọn Ijẹbu kaakiri, agaga Awa Ijẹbu ati agbegbe ẹ.  Lara awọn ohun tawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn lọjọ tọwọ ba wọn naa ni: Ibọn ṣakabula oloju meji,  ọta ibọn rẹpẹtẹ, foonu oriṣiiriṣii mẹfa, faanu OX mẹta, ẹrọ amohundungbẹmu nla kan, kaadi idanimọ ẹgbẹ fijilante (VSO), meji, tẹlifiṣan alalẹmọgiri kan, silinda meji,  ẹwu akọtami kan, ẹrọ to n  ṣatunṣe sina ẹlẹtiriiki (stabilizer),marun-un, aago ti wọn n lu ni ṣọọṣi kan, pọọsi ti wọn n fi ibọn pamọ si ati ọbẹ kan.

Kitikiti ni gbogbo ẹru yii kunlẹ nigba tọwọ ba awọn adigunjale yii, awọn ọlọpaa ṣalaye pe gbogbo ẹ lawọn ti ko fawọn to ni wọn pada.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ yii, CP Iliyasu Ahmed, ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn ole naa lọ sẹka FSARS, ẹsẹkẹsẹ ni aṣẹ ọhun si ti di titẹle, ibẹ ni wọn ti ṣọdun tuntun, ti wọn yoo gba de kootu laipẹ rara.

 

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.