Ṣọja lu aṣọbode pa ni Ṣaki

Spread the love

Ọjọbọ, Tọsidee, ogunjọ, oṣu to kọja yii, ni awọn ṣọja ti 244 battalion, to wa ni Asabari, niluu Ṣaki, kọlu ọkan lara awọn oṣiṣẹ to asọbọde to wa niluu naa, wọn si lu ọmọkunrin ọhun titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun wa pe abule Abungudu, to jẹ kilomita mọkanlelogoji siluu Irawọ, nijọba ibilẹ Atisbo, ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ni nnkan bii aago meji aabọ.

O ṣalaye pe awọn ọmọ orileede Togo ti wọn n ṣiṣẹ agbaṣe labule Abungudu, ni awọn oṣiṣẹ aṣọbode n beere iwe ti wọn fi wọle si orileede yii lọwọ wọn, ṣugbọn ti ko si eyi to ri i ko silẹ ninu wọn.

Awọn oṣiṣẹ yii ni dandan ni ki awọn ọmọ Togo naa sanwo, igbesẹ yii ni a gbọ pe o bi ẹni to gba awọn eeyan naa siṣẹ ninu, to si gba bareke awọn ṣọja lọ pe ki wọn waa ba oun da sẹria fun wọn.

Ṣọja kan to sọrọ naa fun lo paṣẹ fun ọkan ninu awọn ṣọja mi-in torukọ rẹ n jẹ Moses pe ko tẹle ọkunrin naa lọ si abule Abungudu, lai gba aṣẹ lọwọ ọga wọn patapata.

Nitori ẹjọ ti wọn ti ro mọ awọn aṣọbode yii lẹsẹ tẹlẹ, ọkunrin ṣọja yii ko wulẹ beere alaye to fi ko idi ibọn ati koboko to wa lọwọ rẹ bo ọkan ninu awọn oṣiṣẹ yii, Tọpẹ Omiṣakin, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, lẹsẹkẹsẹ ni ẹjẹ si bẹrẹ si i tu jade loju ati imu rẹ. Iṣẹlẹ yii lo ba awọn ara abule naa lẹru, digbadigba ni wọn si gbe ọkunrin ọmọ bibi ilu Ile-Ifẹ yii lọ si ọsibitu Baptist Medical Centre (BMC), to wa niluu Ṣaki, ṣugbọn ibẹ lo pada dakẹ si.

Akọroyin wa ṣabẹwo si ọsibitu naa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu to kọja yii, nibẹ si ni awọn oṣiṣẹ to ba wa sọrọ ti fidi ẹ mulẹ fun wa pe awọn oṣiṣẹ Ajọ Imigireṣan ti n ṣeto lati fi iroyin iṣẹlẹ naa to awọn mọlẹbi rẹ leti.

Gbogbo igbiyanju akọroyin wa lati ri ọga awọn ọmọ ogun bareke yii, Ọgagun P.K Zawaya, sọrọ lo ja si pabo, nitori ṣe lo kọ lati yọju si wa.

Akọroyin wa ri i gbọ pe ṣọja to ṣiṣẹ laabi naa ti wa lahaamọ awọn ṣọja.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ Imigireṣan, Ọgbẹni Salisu Musa, to ba akọroyin wa sọrọ lorukọ ọga agba ẹkun naa, Abubakara Babankanao, sọ pe aṣẹ ti wa lati olu-ileeṣẹ naa to wa l’Abuja pe wọn ko gbọdọ sinku oloogbe naa titi asiko ti iwadii yoo fi pari.

 

 sold

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.