Ṣeyi Makinde ni oun yoo gbogun ti iwa ẹlẹyamẹya bi wọn ba dibo yan oun l’Oyoo

Spread the love

Oludije fun ipo gomina ninu eto idibo oṣu kẹta, ọdun yii, labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ṣeyi Makinde, ti ṣeleri lati gba awọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ laaye lati ṣe ẹsin to ba wu wọn, toun ko si ni i yan ọkankan ninu wọn nipọsin.
O sọrọ yii lasiko to n fọkan awọn ẹlẹsin abalaye balẹ lakooko ipolongo ibo rẹ to waye niluu Otu, nijọba ibilẹ Itẹsiwaju, lẹyin to ti ṣe oriṣiiriṣii ileri fun awọn oludibo lagbegbe  Oke-Ogun, lọsẹ to kọja.

Makinde ni bo tilẹ jẹ pe gbogbo ẹsin ni
Ọlọrun yọnu si, oun yoo faaye gba olukuluku ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ lati ṣe ẹsin to ba wu wọn, ti oun yoo si gbe wọn larugẹ ni kete toun ba ti gba iṣakoso iṣejọba ipinlẹ naa.
Ọlọkaka tilu Ọkaka, Ọba Azeez Ayọọla Ogelende, gba oludije naa nimọran lati tẹle gbogbo ileri rẹ lakooko ipolongo rẹ to ba depo agbara, to si gba awọn oludibo nimọran lati ma ṣe faaye gba jagidi-jagan lakooko ibo.

Oludije ọhun ko ṣai fokan awọn ara agbegbe Oke-Ogun balẹ pe gbogbo ipenija to n koju agbegbe naa paapaa, aisi ọna to daa,
didaku ina ijọba ati iranlọwọ fawọn agbẹ ni oun yoo
mojuto ni kete toun ba gori aleefa.

 

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.