Ṣebi Ọbanikoro lo ti tirafu yẹn

Spread the love

Ko si bi EFCC ṣe fẹẹ ṣe ẹjọ ti wọn tori ẹ mu Ayọdele Fayoṣe yii ti ko ni i ni ọwọ Musiliu Ọbanikoro ninu. Bi EFCC yoo ba ri ọna ba yọ, ti wọn yoo si ri Fayoṣe da lẹbi, wọn gbọdọ ri ẹri gidi, nitori awọn lọọya nla nla ti wa ti wọn yoo gbe oriṣiiriṣii irọ kalẹ, ti wọn yoo ni Fayoṣe ko ko owo ẹnikẹni jẹ, owo lawọn yoo gba ni tiwọn. Ṣugbọn ẹni kan wa to le fọ gbogbo irọ ti awọn lọọya yii ba pa, Ọbanikoro yii ni, nitori oun lo fọwọ ara rẹ ko owo fun Fayoṣe. Ẹnu ki awọn lọọya EFCC beere iṣẹ ti Fayoṣe ṣe fun Ọbanikoro to si ko bii biliọnu kan ataabọ owo ijọba waa fun un ni, ati idi to fi jẹ kaaṣi lo ko iru owo bẹẹ rin, ti ko ko o gba banki, ati ẹni to ko owo naa fun un. Bi Ọbanikoro ba ti tu gbogbo eleyii kalẹ, ko si ẹni ti yoo da Fayoṣe duro lọna ẹwọn, tabi ti yoo gba a ti ko ni i da owo pada sapo ijọba. Ṣugbọn EFCC ti mu Ọbanikoro, wọn ti gba owo ṣukẹṣukẹ lọwọ rẹ, wọn gba ọgọrun-un miliọnu ninu bii biliọnu mẹta to ji ko, niyẹn ba sare wọ inu APC, o ni ọmọ Asiwaju Tinubu loun, lati ọjọ naa lo ti di ọkan ninu awọn angẹli igbalode, to n jaye ori ẹ kiri laarin awọn malaeka inu APC. Bẹẹ ole ti Ọbanikoro ja buru ju ti Fayoṣe lọ, ko si si ọna meji ti wọn yoo fi da Fayoṣe lẹbi nigba ti Ọbanikoro ba n rin kiri. Ileeṣẹ EFCC gba pasipọọtu ọwọ ọkunrin naa lati bii ọdun meji sẹyin, ṣugbọn ni bayii, wọn ti da a pada fun un, wọn ni ko maa lọ sibi to ba wu u, niyẹn ba yaa gbera paa, o di Amẹrika, o ni oun n lọọ ṣeto ilera oun. Ko sẹni to mọ ọjọ ti yoo de, ko si sẹni to mọ ọjọ ti wọn yoo ni ki oun ati Fayoṣe jọ waa koju ara wọn. Ẹ ẹ ri i pe EFCC funra wọn lo n ba ẹjọ ara wọn jẹ, awọn gangan ni olori alai-nikan-an-ṣe.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.