Ṣebi ẹyin naa gbọ ohun ti iyawo Buhari wi

Spread the love

Alhaja Aishat Buhari, iyawo olori orilẹ-ede yii, sọrọ kan lọsẹ to kọja yii, ọrọ naa n da gbogbo ile ijọba ru titi di bi a ṣe n sọ yii ni. Nigba ti obinrin naa n lọ si ibi ti yoo ti sọrọ yii ni ilu Abuja, ọtọ ni iwe ti wọn ko le e lọwọ pe ko ka lọhun-un, ṣugbọn nigba to debẹ, ọrọ to wa lẹnu ati lọkan rẹ lo sọ. Koda o ni oun mọ pe inu awọn eeyan oun bii iyawo Ọṣinbajo, bii awọn ẹṣọ oun ko ni i dun si ohun ti oun sọ yii, ṣugbọn oun gbọdọ sọ ọ. O ni ki gbogbo aye mọ pe ki i ṣe ọkọ oun, iyẹn Buhari, lo wa nidii gbogbo iṣoro to n ba Naijiria yii o, o ni awọn eeyan meji kan ni wọn wa ninu ijọba naa ti wọn n da a ru, awọn ni wọn ko si jẹ ki ọkọ oun ṣe ohun to yẹ ko ṣe. Iṣoro ni pe ko darukọ awọn eeyan meji yii, bo tilẹ jẹ pe gbogbo ilu mọ pe awọn ti wọn sun mọ Buhari ju ni, iyẹn awọn agbalagba meji kan ti wọn n ba a ṣiṣẹ, ti wọn si tun jọ jẹ ọmọ adugbo kan naa. Amọ nnkan to wa nibẹ ni pe Aishat ko le ri ọkọ rẹ ti, ko si le ri ohun to n lọ ti, nigba to jẹ nibẹ ni wọn jọ n gbe, ninu ile ni wọn jọ n sun, ko si sẹni ti yoo sun mọ ọn ju ọkọ rẹ lọ. Iṣe ilu, tabi iṣakoso orilẹ-ede nla bii Naijiria yii ki i ṣe iṣẹ ti olori ilu yoo kan deede fa le awọn kan lọwọ bẹẹ, ti yoo si maa ni ki wọn ṣe ohun to wu wọn. Gbogbo nnkan lo n daru lojoojumọ, ko si ẹni kan to le da nnkan kan ṣe, awọn minisita ko ri Aarẹ Buhari funra rẹ soju, afi lẹẹkọọkan to ba yọju si wọn, ko si agbekalẹ eto ti ijọba yii n tẹle, kaluku n ṣe ohun to ba ti wa si i lọpọlọ ni. Ilu yii ko le roju bẹẹ yẹn, ohun aburu oriṣiiriṣii ni yoo maa ṣẹlẹ, bo ba si n ṣẹlẹ bayii, afaimọ ki nnkan wa ma bajẹ ju bayii lọ. Ki Ọlọrun ṣaanu wa o.

 

 

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.