Ṣebi ẹ ri Saraki atawọn oloṣelu Abuja

Spread the love

Lara ohun ti a n wi ree, nigba ti olori ilu ba ti n tẹ ofin loju, ti ko si mu un lo, awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin naa yoo maa ṣe awọn ohun to wu wọn ni. Iwa ti awọn eeyan bii Saraki hu lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu wọn to kọja, PDP, ki i ṣe iwa ọmọluabi, iwa ole ati olojukokoro ni, o si daju pe ofin ko faramọ awọn iwa agabagebe bẹẹ. Saraki jade, o n pariwo kiri pe oun fẹẹ du ipo aarẹ Naijiria, oun loun yoo dupo naa lorukọ PDP. Nitori irin raurau yii, gbogbo ile igbimọ aṣofin, nibi to ti yẹ ki wọn maa ṣe ofin idagbasoke fun Naijiria, ni wọn ti pa, ti wọn ni awọn ko ṣiṣẹ fun igba diẹ, ṣugbọn ti igba diẹ naa di igba pipẹ. Wọn da ile aṣofin naa ru debii pe awọn ọmọ Naijiria n beere pe ṣe a ni aṣofin ṣaa. Bẹẹ, owo oṣu wọn ko duro o, gbogbo igba ti wọn fi n ṣeranu kiri yii ni owo oṣu ati awọn ajẹmọnu wọn n lọ, wọn si n gba a. Ṣugbọn ni gbara ti wọn dibo tan ti Saraki ko wọle, oun ati awọn gomina mi-in, Saraki sare pada si Kwara, o si lọọ mu fọọmu ti wọn ti fọgbọn alumọkọrọyi gba silẹ fun un tẹlẹ, o ni oun yoo du ipo ọmọ ile-igbimọ aṣofin. Saraki ti ṣe gomina fọdun mẹjọ, o si ti ṣe ọmọ ile-igbimọ aṣofin fọdun mẹjọ mi-in, ọdun mẹrin mi-in lo tun n palẹmọ yii, ibeere to si yẹ ki eeyan beere naa ni pe ṣe ọkunrin yii ko ni iṣẹ kankan laye rẹ to le fi jẹun ju oṣelu lọ ni. Bi wọn ṣe pọ ninu PDP ree o, ohun ti awọn aye si ṣe sọ ẹgbẹ wọn naa lẹnu ree, ti wọn ni ẹgbẹ ole lẹgbẹ wọn. Bawo ni eeyan yoo ṣe maa tan araalu jẹ bẹẹ, ti wọn yoo ba ilu jẹ nitori wọn fẹẹ du ipo, ti wọn yoo du ipo kan tan ti wọn yoo sare bẹ mọ omi-in lai ka awọn eeyan ilu to ku si, lai fi ti araalu ṣe. Loju awọn eeyan bii Saraki yii, ọbọ ni awọn eeyan ilu, ibi ti eeyan ba le rẹ wọn jẹ de ni ko rẹ wọn jẹ, koda, bi wọn ba fẹẹ rẹ wọn ta ki wọn tete ta wọn, ko si ohun ti wọn yoo ṣe. Ọpọlọpọ iwa oriburuku ti wọn n hu yii ni ofin Naijiria lodi si, ṣugbọn ko sẹni ti yoo mu wọn si i. Bẹẹ, bo ba jẹ ki i ṣe pe awọn olori wa naa n huwa ti ko bofin mu, ti wọn n tẹ oju ofin mọlẹ kiri ni, yoo ṣoro fun awọn eeyan lasan yii lati maa sọ ara wọn di eeyan gidi, ti wọn yoo si maa fi iwa ọdaran ọwọ wọn koba gbogbo araalu. Ọjọ kan n bọ ti Ọlọrun yoo fi iya nla jẹ awọn oloṣelu yii, ọpọlọpọ awọn aṣebajẹ yii ni yoo si parẹ tiran-tiran.

(57)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.